Yọmi Fabiyi bimọ ọkunrin, ni Tọpẹ Alabi ba rọjo adura le ọmọ tuntun lori

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i ṣi asọ loju obinrin to bimọ naa fun un, iroyin ayọ to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa to n ti Baba Ijẹṣa ti wọn mu fẹsun ifipabanipopọ kan, Yọmi Fabiyi ti bi ọmọkunrin lanti lanti.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Yọmi kede pe, ‘‘Ogo ni fun Ọlọrun o, a bi ọmọkunrin lantilanti. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun alagbara, awọn obi mi lati igun mejeeji, mama mi, Toyin Afọlayan, awọn ọrẹ, aladuugbo fun atilẹyin wọn. Mama mi, ireti mi ni pe inu yin yoo dun nibikibi ti ẹ ba wa. Ẹ ti tun di iya-iya ọmọ.’’

Lẹyin eyi ni Yọmi gbe fidio ibi to ti wa lọsibitu sori ikanni Instagraamu rẹ, nibi ti o ti n kọrin, to n jo, to si ṣafihan oju ọmọ naa ati iya rẹ.

Bakan naa ni olorin ẹmi nni, Ajihinrere Tọpẹ Alabi, wa lọsibitu pẹlu Yọmi ati iya ọlọmọ, nibi to ti rọjo adura le ọmọ tuntun naa lori.

Yọmi Fabiyi dupẹ lọwọ awọn to ti n pe e ki lori ẹbun tuntun t’Ọlọrun ṣẹṣẹ fun un yii. Bẹẹ lo sọ pe baba iya ati ọmọ wa lalaafia.

Tẹ o ba gbagbe, oyinbo kan to n gbe ilu London ni Yọmi ṣegbeyawo pẹlu lọdun diẹ sẹyin, ṣugbọn ajọṣe naa ko tọjọ fun awọn aigbọra ẹni ye to ṣẹlẹ laarin wọn.

Leave a Reply