Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn oludije mẹtẹẹta ti wọn gba fọọmu lati dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Gomina Adegboyega Oyetọla, Ọnarebu Lasun Yusuf ati Alhaji Moshood Adeoti, ti fara han niwaju igbimọ to n ṣayẹwo ohun gbogbo nipa wọn niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Ṣekiteriati apapọ ẹgbẹ wọn ni eto naa ti waye.
Ilu Iragbiji, niha Aarin-Gbungbun Ọṣun ni Oyetọla ti wa, saa keji lo si n gbero lati lọ fun. Ọmọ bibi ilu Ilobu, niha Aarin-Gbungbun Ọṣun ni Ọnarebu Lasun Yusuf, nigba ti Alhaji Adeoti wa lati ilu Iwo niha Iwọ-Oorun Ọṣun.
Lẹyin ti Gomina Oyetọla kuro lọdọ awọn igbimọ naa niluu Abuja lo fọwọ sọya fun awọn oniroyin pe oun loun kunju osunwọn ju lọ laarin awọn oludije mẹtẹẹta.
O ni iṣẹ rere tijọba oun ti ṣe nipinlẹ Ọṣun laarin ọdun mẹta pere ti jẹ ki awọn araalu fẹran oun, to si jẹ didun inu wọn pe ki oun pada ṣe gomina lẹẹkeji.
Gomina fi kun ọrọ rẹ pe abẹwo ti oun n ṣe kaakiri awọn ẹkun idibo mẹsẹẹsan to wa nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ ti jẹ koun mọ pe digbi lawọn araalu duro ti iṣejọba oun.
O ni oun ko bẹru, bẹẹ ni mimi kan ko mi oun nitori oun mọ daju pe oun lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọṣun yoo dibo yan ninu idibo abẹle ti yoo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, ti a wa yii.