Nitori to ba ọrẹbinrin rẹ ṣedanwo, Fasiti Ilọrin le akẹkọọ rẹ kan danu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Kayeefi lọrọ naa jẹ nigba ti iroyin de si etiigbọ awọn eeyan pe akẹkọọ kan ti wọn forukọ bo laṣiiri to wa ni ipele asekagba (400 Level), Fasiti Ilọrin, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọọ ba ọrẹbinrin rẹ to wa ni ọdun kin-in-ni, (100 level) ṣedanwo kọọsi kan ti wọn pe ni GNS 112. Lasiko to n ṣedanwo naa lọwọ tẹ ẹ, ni awọn alaẹ ileewe ọhun ba le e danu fun ẹsun magomago lasiko idanwo.

Oniruuru ọrọ lo ti wa gba oju opo ayelujara bayii lori idajọ ti awọn alaẹ ileewe gbe kalẹ. Awọn kan sọ pe o yẹ ki wọn kan fiya jẹ ẹ diẹ ni, ko yẹ ki wọn le e danu, nigba ti awọn miiran sọ pe idajọ to dara ni, ohun oju wa ni oju ri. Awọn kan tilẹ sọ pe wọn sa si i akẹkọọ naa lati ile ni, nigba tawọn miiran tun sọ pe ifẹ lo n pa a bii ọti. Sugbọn eyi o wu a wi, ọbẹ bu ni lọwọ, a ju ọbẹ silẹ, ọbẹ ti ṣe ohun to fẹẹ ṣe. Wọn ti le kuro nileewe na ni orin ti ọpọ eeyan n kọ.

 

Leave a Reply