Yẹmi Adedeji
Afaimọ. Afaimọ. Afaimo ni ko ni i jẹ lẹyin ti wọn ba dibo Naijiria tan, tabi ko jẹ lẹyin ti ijọba Buhari yii ba kogba wọle ninu oṣu karun-un, ọdun 2023, ni wọn yoo too fi ajijagbara ọmọ Yoruba to n ja fun ẹtọ awọn eeyan rẹ bayii, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo aye n pe ni Sunday Igboho silẹ o.
Ifimufinlẹ ALAROYE fi han gbangba pe yoo ṣoro ki ọkunrin naa too ribi fi ẹsẹ ara rẹ rin jade, bi awọn eeyan wọnyi ba ṣi wa nile ijọba. Ohun ti ọpọ eeyan ro ni pe ijọba Bẹnnẹ nikan lo n lo agbara rẹ le Sunday Igboho lori, awọn ni wọn ko fẹẹ fi i silẹ.
Ohun ti ọpọ si ro ni pe ijọba orilẹ-ede Naijiria ni wọn n fun okun mọ Igboho lọrun pe ki wọn ma tu u silẹ, ko wa lọdọ wọn nibẹ. Ṣugbọn ọrọ naa jọ bẹẹ ni, ko ri bẹẹ tan, ohun to si wa lẹyin ẹfa paapaa ju eje lọ ni, awọn kinni kan wa to ṣokunkun, o si le diẹ ki ALAROYE too ri wọn tu jade.
Ni ọsẹ to kọja yii, ọkunrin lọọya kan to wa lara awọn ti wọn ṣe ẹjọ awọn ọmọlẹyin Igboho ti wọn ko nile ẹ lọjọsi, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, jade, o ni wọn ti fẹẹ fi Igboho silẹ, ko ni i pẹẹ jade rara. Ṣugbọn ko ju ọjọ keji to sọrọ lọ, iroyin to jade ni pe awọn adajọ ilẹ Bẹnnẹ, ni Kutọnu, ti tun fi ọjọ kun ọjọ ti ọkunrin naa yoo lo lọgba ẹwọn, wọn ni fun oṣu mẹfa mi-in, ko sẹni ti yoo ri Sunday Igboho nigboro. Ọrọ naa di itiju nla si Ọlajẹngbesi lọrun, nitori niṣe lo da bii pe ko mọ ohun to n lọ rara, ko tiẹ mọ ohun to n lọ nipa ọrọ naa, awọn eeyan si ro pe o kan n sọ isọkusọ kan lẹnu ni. Bẹẹ ohun meji lo jẹ ki Ọlajẹngbesi sọrọ jade. Oun ti ro pe nigba ti oṣu mẹfa ti wọn ti fi Sunday pamọ ti fẹẹ pe, ti wọn ko si ri ẹsun iwa ọdaran kankan ka si i lẹsẹ, wọn yoo fi i silẹ bi oṣu mẹfa naa ba ti n pe, nitori ko si idi kan ti wọn yoo fi da a duro mọ. Ohun ti Ọlajẹngbesi fi pariwo pe wọn fẹẹ fi Igboho silẹ niyẹn.
Bẹẹ ki i ṣe oun nikan lo mọ nipa ọrọ yii. Awọn eeyan ilu oyinbo kan wa ti wọn ti wa nidii ọrọ Igboho yii lọjọ to ti pẹ, awọn ni wọn n nawo, ti wọn n nara, ti wọn si wa ninu awọn ti wọn ṣeto lọọya ọmọ Bẹnnẹ to wa ni Faranse, to n ba wọn ṣe ẹjọ Igboho lati ọdọ wọn. Awọn yii ti sọ fun ALAROYE pe inu awọn o dun si Ọlajẹngbesi rara, wọn ni ko yẹ ko pariwo ọrọ naa sita nitori ko sẹni to ran an niṣẹ yẹn. Wọn ni awọn ko sọ fun un ko ba ẹnikẹni sọrọ naa rara, nitori iṣẹ abẹlẹ lawọn n fi ọrọ naa ṣe, ohun to si fa a to fi lọọ kede ọrọ naa fawọn oniroyin, oun nikan lo ye. Nigba naa ni ALAROYE beere lọwọ awọn yii pe ṣe loootọ ni Igboho ti fẹẹ jade ni. Awọn naa ni loootọ ni, ati pe eto gbogbo ti wa nilẹ pe bo ba ti n jade bayii, orilẹ-ede Jamani lawọn n gbe e lọ taara, nibi tawọn yoo ti le tọju ẹ, ko too waa maa ba ija Yoruba Nation ẹ lọ.
Wọn ni awọn ti ṣeto kalẹ debii pe ẹronpileeni ti yoo gbe e yoo ti wa nilẹ, awọn yoo si ri i pe ko ba ẹnikẹni sọrọ titi ti yoo fi de orilẹ-ede Jamani, nitori awọn mọ ete ati erongba buruku ti ijọba Buhari ni si i ni Naijiria, nitori ẹ ni awọn ko ṣe ni i fi aaye silẹ ki erongba wọn ṣẹ. Wọn ni awọn mọ pe to ba ti de Jamani bayii, ko si ohun ti ijọba Naijiria tun le fi i ṣe mọ, nitori yoo ti bọ lọwọ wọn. Eto tawọn ti to kalẹ niyi, awọn naa si n reti ki wọn deede gbọ pe wọn ti fi Igboho silẹ, kawọn si palẹ ẹ mọ, kawọn ara Naijiria too mọ nnkan kan ni. Ṣugbọn lojiji lawọn naa gbọ pe wọn ti fi ọjọ kun ọjọ ti Igboho yoo lo, wọn ti tun fi oṣu mẹfa mi-in kun. Itumọ eyi ni pe ko si ohun kan ti yoo ṣẹlẹ, Igboho yoo lo oṣu mẹfa mi-in pe perepere; ki ẹnikẹni too le sọ nipa ẹ, tabi sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si i. Ohun to si fa ariwo tuntun tawọn eeyan n pa niyi.
Ki lo de ti ijọba Bẹnnẹ ṣe fi ọjọ kun ọjọ ti Igboho yoo lo lọgba ẹwọn, ki lo de ti wọn ko fi ọkunrin naa silẹ ko maa lọ, agaga nigba ti wọn ko le ko ẹri, tabi mu ohunkohun jade pe o ṣe fawọn lorilẹ-ede awọn. Akokọ ni pe ni orilẹ-ede Bẹnnẹ, ofin tiwọn faaye gba wọn lati mu eeyan kan ti mọle, ti wọn yoo si maa yọ ọ jade loṣu mefa mẹfa titi ọdun marun-un yoo fi pe e. Eyi ni pe ti wọn ba mu ẹni kan, ti awọn ọlọpaa ba ni awọn ṣi n ṣe iwadii ẹ lọwọ, wọn lẹtọọ ati agbara ati ti i mọle titi oṣu mẹfa, ko gbọdọ ju oṣu mẹfa lọ. Ṣugbọn ti oṣu mẹfa ba pe, ti wọn ba tun gbe e dele- ẹjọ, ti awọn ọlọpaa ba ni awọn ṣi n ba iwadii awọn lọ, ti wọn ba tun beere fun oṣu mẹfa mi-in, wọn yoo fun wọn, wọn si le ṣe bẹẹ fun ọdun marun-un gbako. Bi wọn si ti i mọle bẹẹ, ko si ohun ti ẹnikan le ṣe si i, nitori wọn ko ṣe ohun to lodi si ofin ilẹ wọn.
Ohun ti wọn ṣe fun Igboho ree. Wọn ko jẹ kawọn lọọya rẹ tabi oun naa daamu de ile-ẹjọ, ohun ti wọn ṣe ni pe niṣe ni awọn ọlọpaa faili iwe pe awọn ko ti i pari iwadii awọn, awọn adajọ naa si sare da a pe ko si wahala kan nibẹ, oṣu mẹfa ti wọn beere fun yii, awọn yoo fun wọn kia. Bẹẹ ni wọn yẹ oṣu mẹfa mi-in lu Igboho, yoo si wa ni Bẹnnẹ titi ọjọ naa ni, ninu ọgba ẹwon wọn ni Kutọnu. Loootọ ni Igboho ti gba ile-ẹjọ lọ, to pe ijọba Bẹnnẹ lẹjọ, to ni ki wọn dajọ pe oun o lẹbi ẹsun kan, ko si si idi ti wọn fi gbọdọ ti oun mọle mọ, ki wọn tu oun silẹ koun maa lọ, ki wọn si san owo itanran ifiyajẹni-lainidii ti wọn ṣe soun. Miliọnu kan owo dọla ni ẹjọ ti Igboho pe, ile-ẹjọ ajọ awọn orilẹ-ede Iwọ-Oorun Afrika ti wọn n pe ni ECOWAS lo pe ẹjọ naa si, nibi to jẹ ẹjọ ti wọn ba da nibẹ, aṣẹ ti wọn ba pa, gbogbo orilẹ-ede West Afrika lo gbọdọ tẹle e.
Loootọ ẹjọ naa yoo daa ti wọn ba tete gbọ ọ, ti wọn si da a, ṣugbọn mo n bọ wa Ọlọrun ni, ko ya logun ọdun, lati gbọ ẹjọ naa ati lati da a ki i ṣe ohun to ya bọrọ rara. Ohun to si fa a ni pe ọrọ oṣelu lọrọ naa, oju oṣelu ni wọn yoo fi wo o, oju oṣẹlu ni wọn yoo si fi gbọ ọ. Itumọ eyi ni pe bo ba jẹ ECOWAS ni yoo dajọ Igboho, ọna yoo pẹ si i. Bi wọn ba bẹrẹ lati gbọ ọrọ naa ni ile-ẹjọ apapọ awọn orilẹ-ede yii, awọn ti wọn ṣe ọna bi Sunday Igboho ṣe pẹ nitimọle Bẹnnẹ yii, awọn naa ni wọn yoo ṣe e ti ko fi ni i tete jade, tabi ti ko ni i ri idajọ to yẹ fun un gba. Ohun ti iwadii ALAROYE mu jade ni pe ijọba Bẹnnẹ ko lẹbi ọrọ naa, koda ti Igboho ni wọn n ṣe. Nigba ti ọrọ ba si de oju rẹ ti wọn ba tu awọn aṣiri ti wọn mọ, ati idi ti wọn fi n ṣe ohun ti wọn n ṣe yii, ko sẹni ti yoo le da wọn lẹbi ohun ti wọn ṣe fun Igboho, wọn yoo kan saara si wọn ni.
Loootọ ni wọn fẹẹ fi Igboho silẹ lọsẹ to kọja! Wọn fẹẹ fi i silẹ ko maa lọ. Wọn ti ṣewadii, wọn si ti ri i pe ko sohun kan to fi ṣẹ sofin ilu awọn. Bẹẹ ni yatọ si ohun tawọn eeyan n wi, ti wọn n sọ pe ijọba Naijiria lo n kọwe si wọn ni Bẹnnẹ pe ki wọn ma fi Igboho silẹ, ọtọ ni ohun to n lọ o jare. Ijọba apapọ Naijiria ko kọwe si wọn ni Bẹnnẹ, koda wọn ko ṣe bii ẹni to mọ ohun to n lọ rara, wọn kan duro si ẹgbẹ kan wọn n woran ni. Ọrọ yii fu awọn ara Bẹnnẹ lara pupọ, paapaa ijọba wọn. Iba dara ti wọn ba mọ ohun to wa lọkan awọn ti wọn n ṣejọba ni Naijiria, eleyii yoo le jẹ ki wọn mọ ohun ti wọn yoo ṣe. Ṣugbọn ijọba Naijiria ko ṣe bii ẹni pe ọrọ Igboho ka awọn lara, wọn n ṣe bii ẹni pe ko kan awọn, wọn o si beere ohunkohun lọwọ awọn ti Bẹnnẹ to mu Igboho dani. Nigba naa ni awọn ara Bẹnnẹ yii mọ pe kinni kan wa lọkan ijọba Naijiria ti ko daa.
Ohun ti iwadii ija naa kọkọ fi han ni pe bawọn ba fi Sunday Igboho silẹ, bi wọn ko ba ji i gbe, wọn yoo pa a ko too le ribi sa jade. Bẹẹ ni ki i ṣejọba Naijiria lo wa nidii ọrọ yii, o jọ pe wọn ti gba awọn eeyan ni Bẹnnẹ ti wọn yoo ṣiṣẹ naa, awọn yii naa ti wọn si jẹ ọmọ orilẹ-ede naa mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe. Bi wọn ba ti n fi Sunday Igboho silẹ ni awọn ti wọn n ṣọ ọ yoo ṣu u rugudu, ko si si ibi to le wọ ti wọn ko ni i mu un ko too di pe yoo raaye sa jade. Ki i ṣe pe wọn yoo gbe e pa, ẹnu ọna ibode Naijiria ni wọn yoo ti i si, ki wọn si too fi i silẹ, wọn yoo ri i pe ọwọ awọn agbofinro ti Naijiria ti to o. Nigba naa ni awọn yoo pari iṣẹ tiwọn, ti awọn ti Naijiria yoo si bẹrẹ, ti wọn yoo le mu un ni gidi-gannku. Bi wọn ba gbe Sunday Igboho wa si Naijiria, ko daa, nitori ohun aburu meji lo le ṣẹlẹ si i, awọn ti wọn si n wa a ti pari eto lori awọn nnkan wọnyi, yoo ṣoro ko too ja ajabọ.
Akọkọ ni ki wọn mu un, ki wọn fi i pamọ lẹyin ti wọn ba ti i jẹ ẹ niya, ki wọn si gbe e wa sile-ẹjọ nitori ariwo. Ilẹ-ẹjọ ti wọn fẹẹ gbe e wa naa, ki i ṣe nitori ohunkohun ki wọn le fi gba idajọ pe ẹjọ rẹ fẹẹ bẹrẹ ni, lẹyin eyi ni wọn yoo ṣe bi wọn ti ṣe Nnamdi Kanu, ti wọn yoo fi i pamọ, ti wọn yoo maa fi eni doni-in, fi ọla dọla, lori ẹjọ rẹ, ti wọn ko si ni i fi i silẹ titi ti wọn yoo fi ṣeto idibo wọn tan, tabi ti ijọba Naijiria ti awọn Buhari n ṣe yii yoo fi kogba wọle. Ko si ile-ẹjọ kan ti yoo da ẹjọ rẹ pe ki wọn fi i silẹ, nitori oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn yoo maa ka si i lẹsẹ, titi dori ẹsun ipaniyan, idigunjale atawọn ẹsun wuruwuru mi-in ti wọn ti ṣeto rẹ silẹ fun un. Idi awọn ẹsun yii ni wọn yoo wa titi ọjọ yoo fi lọ, wọn ko si ni i fi i silẹ titi. Bi wahala awọn eeyan ba fẹẹ pọ nidii ọrọ rẹ ju, wọn yoo dajọ ẹwọn fun un, bi ko si jẹ ẹwọn gbere, yoo jẹ ẹwọn ọlọdun gbọọrọ
Ṣugbọn kekere niyẹn lẹgbẹẹ iroyin mi-in to tẹ awọn ara Bẹnnẹ yii ati awọn agbaagba ti wọn n ja fun ẹtọ Igboho leti. Eyi si ni ti ikoriira ti wọn ni awọn agbofinro DSS ni fun un. Awọn ti wọn lọ sile Igboho ni ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2021, ti wọn paayan, ti wọn ba gbogbo mọto rẹ jẹ, ti ile-ẹjọ si ti da wọn lẹbi pẹlu pe ki wọn sanwo itanran rẹpẹtẹ fun ọkunrin naa ko ti i dariji Igboho nidii ọrọ yii, ero wọn si ni pe nibi yoowu ti wọn ba ti ri i, wọn yoo ran an sọrun ti ko fẹẹ lọ nijọ naa ni. Ohun kekere ni wọn yoo fi kẹwọ ti wọn yoo si fi yinbọn lu u, tabi wa ọna mi-in lati pa a, ti wọn yoo si jade lati kede pe nigba to n ba awọn agbofinro wọnyi ja lo fara gbọta, to si ba ibẹ ku. Wọn yoo gbe iwadii jade loriṣiiriṣii, ṣugbọn ko sohun ti iwadii naa yoo mu jade, apagbe ni wọn yoo pa a.
Awọn ara ilẹ Bẹnnẹ ko fi taratara gba awọn ọrọ yii gbọ, afi nigba ti ọjọ n sun mọle lati ri Igboho mu, ti aṣiri awọn ti wọn fẹẹ mu un fun ijọba Naijiria tu si wọn lọwọ. Nigba ti aṣiri yii tu paapaa, ijọba Naijiria bẹrẹ si i ranṣẹ pe ohun ti ki Bẹnnẹ ṣe fawọn ni pe ti wọn ba ti da a silẹ bayii, ki wọn mọ ọna ti wọn yoo fi gbe e wa si ẹnuubode Naijiria, wọn si le fa a le awọn lọwọ nitori o lẹjọ lati jẹ lọdọ awọn. Bẹnnẹ fẹ kawọn ijọba Naijiria kọwe ranṣẹ lori eleyii, wọn si fẹ ki wọn to gbogbo ẹsun ti wọn ni ọkunrin yii ṣẹ lẹsẹẹsẹ kawọn le mọ ibi tawọn yoo ba mu un. Ṣugbọn nigba to ṣe pe ijọba Naijiria ko ni ẹṣẹ gidi kan, to jẹ wọn kan n fi àtamọ́ mọ àtamọ̀ ni, ti ile-ẹjọ si ti da awọn DSS ti wọn lọ sile ọkunrin naa lẹbi, wọn o le kọ ẹsun kankan ranṣẹ sita pe awọn n tori ẹ wa Igboho, eyi ni wọn ko si ṣe fun awọn ara Kutọnu naa ni iwe kankan.
Nitori pe ijọba orilẹ-ede naa ko fẹẹ ṣe ti awọn Naijiria ṣaa, wọn n gbero pe ti ko ba ti si wahala kankan nibi kan, awọn le fa Igboho le Naijiria lọwọ, ki wọn lọọ maa yanju ọrọ naa lọdọ ara wọn. Eyi ni wọn n mura lati ṣe, ti wọn si ti pinnu pe kawọn fa Ijẹṣa le onidilaali lọwọ, ki wọn yọwọ kuro ninu ọrọ Gambari ati Fulani, ohun to ba wu wọn ki wọn fi ara wọn ṣe. Eto ti wọn ti ni ree, ṣugbọn ibi ti wọn ti n ronu bẹẹ ni Minista fun eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami, ti ta wọn lolobo. Loootọ ki i ṣe awọn lo dari ọrọ si, ṣugbọn ọrọ to sọ naa fi han pe ti wọn ba mu Igboho ni Naijiria, bi wọn ko ba pa a, wọn yoo ju u sẹwọn gbere, tabi ki wọn sọ ọ di alaabọ ara. Ati pe bi awọn ko ba ṣọra, ori awọn ni wọn yoo pada da gbogbo ọrọ naa le, ti wọn yoo ni ijọba orilẹ-ede Bẹnnẹ lo pa Sunday Igboho. Lọrọ kan, ọrọ ti Malami sọ lo mu awọn ijọba Bẹnnẹ ronu piwada lori ọrọ Igboho.
Malami sọ pe bi awọn ti wọn n pariwo Yoruba Nation fẹ bi wọn kọ, bi Igboho sa lọ ju bẹẹ lọ, to ba ti le da ẹsẹ wọ Naijiria, lọgan ni awọn yoo gbe e, ti yoo si jẹjọ gbogbo iwa ibajẹ to ba hu pata ati awọn nnkan aṣiri mi-in to tun ṣe. Malami ni ọdaran bii Kanu ni Sunday Igboho, bi awọn si ti ṣe Kanu, to wa ninu ahamọ to n jẹjọ yii, bẹẹ naa lawọn yoo ṣe Igboho nigbakigba tawọn ba ti ri i mu. Ọrọ naa ye awọn ara orilẹ-ede naa ju bẹẹ lọ, ohun ti wọn si mọ to da wọn loju ni pe ko si bawọn ti le fi Igboho silẹ ti ko ni i pada bọ sọwọ Naijiria, nitori bawọn ba gbiyanju lati daabo bo o, Naijiria yoo binu, nitori wọn yoo beere idi tawọn fi n ṣe bẹẹ lọwọ awọn. Ko si ohun meji ti Malami atawọn eeyan tirẹ n fẹ ju ki Sunday Igboho ma si ni gbangba lọ. Bawọn ṣe ti i mọle ni Kutọnu, o tẹ awọn lọrun, bo si jẹ Naijiria naa lawọn ti i mọ, deede ni.
Ohun tawọn fẹ ni pe ko ma si nigboro, nitori wọn mọ pe ti Igboho ba wa laarin ilu, yoo ṣoro ki eto idibo tawọn n mura rẹ yii too ṣee ṣe. Ọna pe ki ọkunrin ajijagbara naa ma waa da eto tawọn n ṣe ni tawọn lati fi ọgbọn gbejọba fẹlomi-in lẹyin Buhari lawọn n ṣe. Bi wọn mu Igboho naa, ohun ti wọn yoo ṣe naa ni lati ri i pe ko jade sita, ko si ri ẹnikẹni ba sọrọ titi digba ti wọn yoo fi dibo, ti wọn yoo si gbe ijọba silẹ fẹni to ba wọle. Bo ba jẹ itimọle nikan ni, o ṣee ṣe ki ijọba Bẹnnẹ ma tori ẹ binu tabi ki wọn ma daamu ara wọn lori ọrọ okunrin yii, ṣugbọn iroyin pe wọn le pa a tabi kijọba sọ ọ di alaabọ ara titi aye lo ba awọn eeyan naa lẹru, bẹẹ ni aanu si ṣe wọn, ohun ti wọn ṣe gbọrọ sawọn agbaagba kan ti wọn wa lẹyin Sunday Igboho lẹnu ree, ti wọn si sọ pe o ṣe anfaani ki Igboho jokoo sibi to wa naa jẹẹ!
Ohun to fa a ti ko fi si ọna ti Sunday Igboho yoo fi jade lọdọ awọn ara Bẹnnẹ titi di ọdun to n bọ ree, nitori bi ọjọ itimọle rẹ ba ti n pe ni wọn aa maa fi omi-in kun un, wọn ko si ni i fi i silẹ, afi ti wọn ba ri i pe ijọba Naijiria ko mura lati pa a mọ, tabi lati sọ ọ di alaabọ ara. Ko si iwadii kankan ti ijọba Bẹnnẹ n ṣe lori ọrọ Igboho mọ, bi ko si si ipinnu ti wọn ṣe lati ma fa ọkunrin yii fun iku ojiji, wọn yoo ti da a silẹ pe ko maa gba ibi to ba fẹ lọ. Ṣugbọn wọn ti pinnu lati mu Sunday Igboho pamọ nitori Naijiria, amọ bi wọn ko ṣe ni i jẹ ko wa si Naijiria, bẹẹ ni wọn ko ni i jẹ ko lọ si orilẹ-ede mi-in, nibi ti oju awọn ko ti ni i to o. Awọn ti wọn wa nidii ọrọ yii ti wọn jẹ agba ajijagbara ati awọn igilẹyin ọgba fun Igboho paapaa ti ni ki wọn ma reti ẹ nile lasiko yii rara, wọn ni o san ko wa laaye nibi to wa ju ki wọn mu un wale lati waa pa lọ.