Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
‘Ajagbe Youngest Nation’ (AYN), ni wọn n pe ara wọn. Ọmọ ileewe Ajagbe High School, Ipẹru-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, ni wọn.
Awọn ni wọn ni wọn n daamu awọn eeyan nileewe naa pẹlu awọn to mule si agbegbe ibẹ. Aipẹ yii lọwọ ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ogun tẹ awọn mẹrin yii ninu wọn.
Olori ikọ Amọtẹkun, Kọmandanti David Akinrẹmi to fi atẹjade iṣẹlẹ yii ṣọwọ s’AKEDE AGBAYE, ṣalaye pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ọmọ ẹgbẹ AYN yii.
O ni awọn ọmọ ẹgbẹ yii lawọn eeyan mọ fun fifi ipa ba awọn ọmọbinrin tọjọ ori wọn ko to nnkan kan lo pọ.
O fi kun un pe awọn mi-in ti wọn ti jade nileewe yii wa ninu ẹgbẹ AYN yii, bẹẹ lawọn kọọkan naa ti wọn ṣi jẹ akẹkọọ nibẹ lọwọlọwọ ṣi wa ninu ẹgbẹ okunkun yii.
Akinrẹmi tẹsiwaju pe inu igbo to wa lẹyin ileewe Ajagbe High School, Ipẹru Rẹmọ, ni wọn ti maa n pade lẹẹmeji laarin ọsẹ, laarin aago mejila kọja iṣẹju mẹwaa si aago kan ku ogun iṣẹju.
Iru ipade bẹẹ ni wọn n ṣe lọjọ kẹsan-an, oṣu keji, ọdun 2022 yii, ti olobo fi ta ikọ Amọtẹkun to wa n’Ikẹnnẹ, pe awọn ọmọde kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ AYN tun ti kora wọn jọ.
Eyi ni ikọ alaabo naa fi gbera wọnu igbo ọhun lọ, nigba ti wọn si debẹ lọwọ ba Ọrẹgbẹsan Idris; ọmọ ọdun mẹtadinlogun, (17) ati Abdul Tọheeb; ẹni ọdun mọkandinlogun (19).
Lẹyin tọwọ ba awọn meji yii ni wọn ṣatọna bi ọwọ ṣe tun ba Ẹsan Kazeem; ẹni ogun ọdun (20) ati Saka Sultan, ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17).
Saka Sultan yii ni wọn pe ni ogunna gbongbo ninu ẹgbẹ naa bo ti kere to, wọn ni ipa pataki lo n ko ninu ẹgbẹ okunkun yii, wọn si ti le e danu nileewe Ajagbe High School, Ipẹru-Rẹmọ.
Ohun ti a gbọ ni pe ero pọ ninu ẹgbẹ AYN yii, awọn ti wọn ṣi jẹ akẹkọọ nileeewe yii atawọn ti wọn ti kuro nibẹ lo kunbẹ fọfọ. Bẹẹ lawọn mi-in wa lati ileewe mi-in nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ yii kan naa, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ AYN.
Gbogbo wọn pata ni ikọ Amọtẹkun lawọn yoo wa jade, bẹẹ ni wọn ni wọn yoo taari awọn tọwọ ba yii sọdọ ọlọpaa, ki wọn lọọ wi tẹnu wọn nibẹ.