Buhari buwọ lu abadofin eto idibo

Faith Adebọla

 Aarẹ Muhammadu Buhari, ti buwọ lu abadofin eto idibo, abadofin naa si ti di ofin ti yoo bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ.

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ni Buhari buwọ lu iwe naa ni gbọngan iṣepade to wa nile ijọba, l’Abuja, olu ilu ilẹ wa.

Lara awọn to pesẹ sibi eto ibuwọluwee naa ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Olori awọn aṣofin apapọ, Ahmed Lawan ati Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila.

Ninu ọrọ to sọ nibẹ, Buhari ni inu oun dun lati ri i pe ọpọ ofin ati atunṣe ti yoo mu eto idibo sunwọn si i lo wa ninu ofin tuntun yii. ‘‘Bi ofin naa ṣe faaye gba ilo imọ ẹrọ igbalode maa mu ilọsiwaju gidi ba eto idibo wa ni Naijiria, o si tun faaye gba awọn ilo imọ ijinlẹ ode oni ati eyi to ṣee ṣe ko waye lọjọ iwaju, o yẹ ka gboṣuba fawọn aṣofin lori eyi.

‘‘Ilo ẹrọ igbalode ati imọ ijinlẹ maa tubọ fidi ẹtọ araalu lati dibo lọna to nitumọ mulẹ.

“Ofin yii yoo tun mu ki eto idibo wa ja geere, ko si ni i si kọnu-n-kọhọ, bẹẹ ni yoo mu adinku ba aawọ ati awuyewuye to maa n su yọ lẹyin eto idibo.

“Bi ofin yii ṣe wa soju taye lonii wa ni ibamu pẹlu ileri ijọba wa lati ṣe awọn nnkan amuyangan ti yoo mu ki iṣejọba awa-ara-wa tubọ fẹsẹ rinlẹ ni Naijiria. Inu mi dun, ni pataki si isọri ikẹrinlelọgbọn, ikọkanlelogoji, ikẹtadinlaaadọta, ikẹrinlelọgọrin ati awọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ.

“Amọ ṣa o, awọn apa ibi kan wa to kọ mi lominu gidi, bii ila kejila, ni isọri ikẹrinlelọgọrin. Lero temi, ofin naa ta ko ẹtọ awọn oloṣelu kan lati dibo tabi ki wọn dibo fun wọn lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ wọn, mi o si ro pe iyẹn wa nibaamu pẹlu ofin ilẹ wa daadaa.”

Tẹ o ba gbagbe, ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Buhari ti kọ lati  buwọ lu abadofin naa, latari bo ṣe n da a pada sileegbimọ aṣofin fun atunṣe kan tabi omi-in, ko too ṣẹṣẹ buwọ lu u bayii. Ọpọ awuyewuye ati iwọde lo si ti waye latari bawọn eeyan ṣe n bẹnu atẹ lu aarẹ fun fifi akoko sofo lati buwọ lu abadofin naa.

Ireti wa pe abadofin tuntun yii ni ajọ INEC yoo fi ṣeto idibo gbogbogboo ọdun 2023, ati awọn eto idibo gomina ti yoo waye lawọn ipinlẹ bii Ọṣun ati Ekiti lọdun yii.

Leave a Reply