Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Gomina ipinle Ekiti tẹlẹ, Oloye Ṣẹgun Oni, ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati ri i daju pe wọn gba kaadi idibo wọn, ki wọn le gba ẹgbẹ Alaburada ati ẹgbẹ Onigbaalẹ to n ṣejọba lọwọ nipinlẹ naa danu.
Ọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọsẹ yii lo sọrọ naa niluu Ado-Ekiti, nigba to n sọ ero rẹ lati dije ninu ẹgbẹ Ẹlẹṣin SDP. O ṣalaye pe ẹgbẹ APC to wa lori aleefa lọwọlọwọ nipinlẹ naa ati ẹgbẹ PDP ni wọn ti kuna lati pese adari to daju fun awọn ọmọ Naijiria.
Gomina tẹlẹri ọhun ni ogọọrọ awọn alatilẹyin rẹ ki kaabọ pẹlu aṣọ alawọ ewe ti foto rẹ ati ẹṣin gẹgẹ bii ami idanimọ ẹgbẹ naa wa.
Awọn alatilẹyin rẹ ati awọn ololufẹ igbakeji rẹ, Ọgbẹni Ladi Owolabi, ni wọn darapọ mọ awọn agbaagba ẹgbẹ naa lati pade Ṣẹgun Oni, ti wọn si da sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ silẹ fun bii wakati meji ni oju ọna Ajilosun, niluu Ado-Ekiti.
Nigba to n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ, Oni sọ pe ẹgbẹ Onigbaalẹ ti Kayọde Fayẹmi n ṣe akoso rẹ nipinlẹ naa lo ti dojuti gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti. O sọ pe ẹgbẹ Ẹlẹṣin ti oun mu wa yii ni yoo jẹ ẹgbẹ itẹsiwaju fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti.
Oni fi da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe ti wọn ba dibo fun oun, oun yoo gba wọn laaye ki wọn le pa aṣẹ to ba wu wọn, gẹgẹ bi oun ṣe ṣe lakooko iṣejọba oun lọdun 2007 si 2010.
Gẹgẹ bo ṣe sọ “Eto idibo yoo waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, gbogbo yin lẹ mọ eleyii, imọran mi si yin ni pe ki ẹ lọọ gba kaadi idibo yin, ki ẹ le le ijọba to wa lori aleefa yii sọnu.
“Kin ni idi pataki ti ijọba wa lori aleefa bayii ko ṣe le pese ohun ti yoo mu aye dẹrun, ẹ jọwọ, ẹ sọ fun wọn pe itẹsiwaju ti de si ipinlẹ Ekiti, ati pe Ṣẹgun Oni ni itẹsiwaju naa.
“Kaadi idibo rẹ ni agbara rẹ, ma ṣe jẹ ki awọn wọnyi tẹsiwaju lati maa fi ẹtọ yin dun yin, ẹ dibo fun ẹgbẹ Ẹlẹṣin, ẹgbẹ yìí nìkan ṣoṣo lo le gba ipinlẹ yii lọwọ oṣi ati aini, ẹ gba wọn danu lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa.”
Oni ṣalaye pe atilẹyin ti oun ti ri lọdọ awọn ọmọ ipinlẹ Ekiti waye nipasẹ ohun rere ti oun ṣe lakooko iṣejọba oun akọkọ, ati bii oun ṣe n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ lakoko.
O ṣeleri pe oun yoo mu eto aabo ni ọkunkundun ati gbigba awọn ọdọ siṣẹ, ati mimu igbega ba iṣẹ agbẹ. Bakan naa lo ni oun yoo ṣe ona ti wọn ba le dibo fun oun.