Faith Adebọla
Akọkọ lara awọn ogunlende ọmọ Naijiria tijọba apapọ ko wale lati orileede Ukraine ti de siluu Abuja, lafẹmọju ojọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta yii.
Okoolenirinwo ati meje (427) awọn ọdọ ati agbalagba ni wọn ba baaluu tijọba fi ko wọn de, nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹwaa si ni baaluu naa balẹ si papakọ ofurufu nla ti Nnamdi Azikiwe, niluu Abuja.
Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe lẹyin odi, Nigerian in Diaspora Commission, Abikẹ Dabiri-Erewa, sọ loju opo tuita (tweeter) rẹ pe: “Akọkọ lara awọn ọmọ Naijiria ta a ko ni Romania ti de si Abuja laaarọ yii.
“Eto n lọ lọwọ lati lọọ ko awọn to ṣẹku lawọn orileede mi-in ti wọn sa lọ, wale. Awọn mi-in lati orileede Hungary yoo de laipẹ.”
Ilu Romania lawọn ti wọn ko wale yii sa lọ, nigba ti ogun to n lọ lọwọ laarin orileede Russia ati Ukraine n le si i. Ọpọ lara awọn akẹkọọ ọmọ Naijiria ni wọn ṣi wa lawọn lorileede alaamulegbe Ukraine, bii Poland, Hungary ati Romania.