Gbenga Amos, Abẹokuta
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni inu ṣi n bi awọn eeyan ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Nura Kazeem, tawọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkada to maa n ja tikẹẹti le titi to fi ko si ẹnu mọto Mazda kan, tiyẹn si tẹ ẹ pa ni Aṣeeṣe, loju ọna Marosẹ Eko si Ibadan.
AKEDE AGBAYE gbọ pe Kazeem to jẹ ọmọ ẹya Hausa naa ko si lẹnu iṣẹ lọjọ yii, wọn ni o ti n mura lati lọ si ilu wọn pẹlu awọn eeyan rẹ kan, o kan wa si adugbo ti wọn ti maa n gbero naa lati waa ṣe nnkan kan ni.
Bi awọn to maa n ja tikẹẹti ṣe ri i ni wọn ti ṣuru bo o gẹgẹ bii iṣe wọn, ti wọn si n beere ẹgbẹta Naira owo tikẹẹti lọwọ rẹ.
Gbogbo alaye ti ọmọkunrin naa n ṣe pe oun ko waa ṣiṣẹ lọjọ naa, ati pe oun n mura lati lọ si ilu awọn ni ko bọ si ibi to daa lara awọn to fẹẹ ja tikẹẹti fun un.
Eyi lo mu ki ọmọkunrin naa ki ere mọlẹ, to n sa lọ lati bọ lọwọ awọn ti wọn fẹẹ gbowo tikẹẹti lọwọ rẹ. Awọn eeyan naa ko koore wahala, niṣe ni wọn tun sa tẹle e ti wọn si n le e lọ. Lasiko to n sa lọ yii lo lọọ ko si ẹnu bọọsi Mazda kan toun n lọ jẹẹjẹ rẹ.
Nitori ori ere ni onimọto naa wa, o ṣoro lati tete ko ijanu mọto rẹ. Nigba ti wọn yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkọ naa ti tẹ Kazeem pa.
Ọrọ naa di wahala, diẹ lo si ku ko da ija ẹlẹyamẹya silẹ laarin awọn Hausa ati Yoruba pẹlu bi awọn Hausa ṣe fa ibinu yọ, ti wọn si koro oju si iwa ti awọn to n ja tikẹẹti naa hu pẹlu bi ọmọkunrin naa ṣe n ṣalaye fun wọn pe oun ko ṣiṣẹ, oun n mura ilu awọn ni, ti wọn si tun n le e lọ titi ti wọn fi le e sẹnu mọto to tẹ ẹ pa naa.