Faith Adebọla
Ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja ti da iwe ẹbẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari kọ si wọn pe ki wọn ṣatunṣe si apa kan ninu ofin eto idibo, nu bii omi iṣanwọ, wọn lawọn o fara mọ ibeere Aarẹ lori ofin naa, wọn wọgi le abadofin to fi ṣọwọ si wọn lori ẹ pẹlu.
Awọn aṣofin naa gbe igbesẹ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, nile aṣofin wọn, nigba ti Olori wọn, Ahmed Lawan pe fun ifọwọsi wọn lati ka abadofin ti Aarẹ fi ṣọwọ naa lẹẹkeji.
Wọn ti kọkọ ka abadofin ọhun fun igba akọkọ lọjọ Tusidee, nigba ti aṣofin kan si pe akiyesi olori wọn si aṣẹ ile-ẹjọ giga Abuja kan to waye lọjọ Aje, Mọnde, ta ko abadofin naa, Lawan ni ko tọna, ko si bofin mu, ki ẹka eto idajọ da awọn aṣofin lọwọ kọ lẹnu iṣẹ wọn, o ni aṣẹ ile-ẹjọ naa ko le da awọn duro.
Ṣugbọn lọjọ Wẹsidee, awọn aṣofin tun ọrọ naa gbe yẹwo, nigba ti wọn si ni ki wọn dibo, boya ki wọn tẹsiuwaju ijiroro lori abadofin naa tabi ki wọn pa a ti, awọn to fara mọ pe ki wọn pa a ti lo pọ ju.
Latari eyi, wọn gba abadofin naa sẹgbẹẹ kan, wọn lawọn o fara mọ ero Ahmed Lawan lati tẹsiwaju lori ẹ, nigba ti ile-ẹjọ ti le paṣẹ ki wọn ma ṣe ṣatunṣe ọhun.
Wọn ni ohun to yẹ, to si bofin mu ni ki ileegbimọ aṣofin naa pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ta ko idajọ ile-ẹjọ giga yii, ki wọn si duro de idajọ ile-ẹjọ naa, boya yoo paṣẹ to yatọ si ti ile-ẹjọ giga.
Adajọ ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja, Onidaajọ Inyang Eden, lo paṣẹ lowurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, pe Aarẹ Muhammadu Buhari, awọn aṣofin apapọ ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami, ko gbọdọ fọwọ kan ofin eto idibo ti aarẹ buwọ lu lọsẹ to kọja, wọn ko si gbọdọ lawọn n ṣe atunṣe kan si i, titi ti igbẹjọ yoo fi pari lori ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, pe ta ko igbesẹ tawọn aṣofin fẹẹ gbe ọhun.
Tẹ ẹ o ba gbagbe, lasiko ti Buhari n buwọ lu abadofin eto idibo naa lọjọ Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keji, lẹyin to ti gboriyin fawọn aṣofin fun iṣẹ rere ti wọn ṣe, o ni isọri kẹrinlelọgọrin (84), ila kejila ninu ofin ọhun kọ oun lominu tori loju toun, o ta ko ẹtọ ati ominira awọn ti wọn yan sipo minisita tabi kọmiṣanna lati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu wọn, o si rọ awọn aṣofin lati ṣatunṣe si ofin naa.
Ọjọ mẹta lẹyin eyi, Buhari kọwe ẹbẹ sawọn aṣofin apapọ, pe ki wọn tete ṣatunṣe si isọri toun sọrọ nipa ẹ naa.