Faith Adebọla, Eko
Ṣe ẹ ranti afurasi ọdaran kan, Chidinma Ojukwu, akẹkọọ Fasiti Eko (UNILAG), to n jẹjọ ẹsun ipaniyan lọwọ lori iku Ọgbẹni Usifo Ataga, lọjọsi? Ọmọbinrin naa lo jawe olubori nibi idije ẹlẹwọn tọ rẹwa ju lọ, eyi to waye lọgba ẹwọn Kirikiri, lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii.
Latigba ti wọn ti mura fun ọdọmọbinrin naa, ti wọn si ṣe e lọṣọọ gẹgẹ bii ‘Omidan Ẹlẹwọn 2022’, ni fọto rẹ ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, ọpọ lo si n bẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn lori bi wọn ṣe fi ọmọbinrin naa saarin awọn olukopa, nigba ti ẹjọ rẹ ṣi n lọ lọwọ ni kootu, wọn ni ko ti i di ẹlẹwọn taara, nigba tile-ẹjọ ko ti i dajọ fun-un.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ẹlẹwọn nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Rotimi Ọladokun, ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ, o ni idije yii atawọn idije mi-in jẹ lati sami ayajọ awọn obinrin lagbaaye, International Women’s Day (IWD), tọdun 2022 yii.
O ni ọdọọdun lawọn maa sami ayẹyẹ naa lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, gbogbo awọn ẹlẹwọn obinrin lo si lanfaani lati kopa, ibaa jẹ pe wọn ṣi n jẹjọ lọwọ, tabi wọn ti dajọ ẹwọn fun wọn, tori lọdọ tiwọn, ẹlẹwọn l’ẹlẹwọn n jẹ.
“Gbogbo awọn ẹlẹwọn to wa ninu sẹẹli kọọkan ni wọn kopa ninu eto kan tabi omi-in. Awọn kan ṣere ori itage, awọn ṣe tiata, ewi lawọn mi-in ke, idije ẹwa, yiyaworan, kikun nnkan lọda, awada kẹrikẹri ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn mi-in ṣe.
Ọpọ ẹbun la fawọn ẹlẹwọn, tori awọn ara ita naa ba wa da si i. O jẹ ara ọna ta a fi n ṣatunṣe aye awọn ẹlẹwọn, gbogbo awọn to wa latimọle wa. Igba to si jẹ ajọdun awọn obinrin, ọgba ẹwọn to jẹ kidaa awọn obinrin lo wa nibẹ lati ṣe e, ki i ṣe t’ọkunrin.
Gbogbo nnkan imura ati ọṣọ ti wọn lo pata, awọn ẹlẹwọn lo ṣe e. Awọn afẹnifẹre kan si wa lati ita ti wọn fun omi-in lara awọn ẹlẹwọn lẹbun, boya lati gba fọọmu idanwo wayẹẹki tabi NECO, tabi ti fasiti (UME) fun wọn.
Ile ẹwọn kan yan aṣoju to maa dije lorukọ awọn ẹgbẹ ẹ. Boya lara awọn aṣoju bẹẹ ni Chidinma jẹ, to fi waa jawe olubori ninu idije naa, mi o le sọ, ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn kopa ninu ajọdun ayajọ awọn obinrin lagbaaye, gẹgẹbi Ọladokun ṣe wi.
Tẹ o ba gbagbe, latinu oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni akẹkọọ to wa nipele kẹta ẹkọ nipa eto ibanisọrọ kari aye ni UNILAG, ti wa lahaamọ awọn agbofinro, kile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to fikalẹ sinu ọgba Tafawa Balewa, l’Erekuṣu Eko, too taari ẹ sẹwọn Kirikiri. Chidinma ni wọn fẹsun kan pe oun ati awọn afurasi ọdaran kan lọwọ ninu iku Ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV, Oloogbe Ataga.