Faith Adebọla, Eko
Ọgbẹni Nice Andrew Omininikoron, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta, awakọ BRT to gbe Oloogbe Bamiṣe Ayanwọla, lalẹ ọjọ to dawati ki wọn too pada ri oku ẹ l’Ekoo, ti dero ẹwọn.
Adajọ O. A. Salawu ti ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa ni Yaba, nipinlẹ Eko, lo paṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii, pe ki wọn ṣi lọọ fi afurasi ọdaran naa sọgba ẹwọn Kirikiri fun ọgbọn ọjọ, ki igbẹjọ rẹ too tẹsiwaju.
Ẹka to n ri si itọpinpin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, State Criminal Investigation Department (SCID), lo bẹ ile-ẹjọ naa pe awọn ṣi n ba iwadii lọ lori ẹsun ti wọn fi kan Ọgbẹni Nice, wọn si tọrọ aaye lati tubọ tuṣu desalẹ ikoko lori ẹsun ọhun, ati pe awọn ọlọpaa ṣi n wa awọn afurasi ọdaran kan ti igbagbọ wa pe wọn mọ si iku ojiji to pa Bamiṣe.
Titi dasiko yii ni awuyewuye ṣi n lọ lori ẹrọ ayelujara lori iṣẹlẹ to waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji ti Bamiṣe, ẹni ọdun mejilelogun, wọkọ BRT to n lọ s’Oṣodi, lati lagbegbe Lẹkki, Ajah, l’Erekuṣu Eko, ṣugbọn awọn amookunṣikan kan ji i gbe ninu ọkọ naa, ko si sẹni to foju kan an, ayafi igba ti wọn lọọ ju oku rẹ sori biriiji Carter lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta yii.
Nice naa sa lọ lẹyin iṣẹlẹ yii, ọjọ kẹfa oṣu Kẹta, kan naa lawọn ọlọpaa ri i mu lagbegbe kan nipinlẹ Ogun, to sa pamọ si, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e.
O sọ lẹyin naa pe oun o mọ nnkan kan nipa iku ọmọbinrin aranṣọ yii, o lawọn mẹrin toun gbe lọna lo fipa wọ ọ bọọlẹ, lẹyin ti wọn yọ ibọn soun nibi toun ti fẹẹ gbe wọn.