Gbenga Amos
Iṣẹ tawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati Zone 2, ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko, ṣe lori bawọn janduku kan ṣe lọọ dana sun Ọba Ọlajide Ayinde Ọdẹtọla, Olu tilu Agodo, nijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti n seso rere latari bọwọ ṣe ba awọn afurasi ọdaran mọkanla ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ yii.
Awọn ọlọpaa lawọn afurasi wọnyi ti n ka boroboro nipa awọn ti wọn ran wọn niṣẹẹbi ọhun, wọn si ti n ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lẹnu iṣẹ iwadii wọn.
Wọn ni iwe ẹsun kan ti ọkan lara mọlẹbi ọba alaye ti wọn pa naa, Ọgbẹni Oku Ọdẹtọla Okunribido, kọ ṣọwọ sileeṣẹ ọlọpaa, lọjọ kẹrin tiṣẹlẹ buruku ọhun waye lo satọna bi wọn ṣe ri awọn afurasi yii mu. Ninu iwe ọhun, wọn fẹsun kan Ọgbẹni Gbeminiyi Ṣotade, ti inagijẹ rẹ n jẹ Okon, wọn loun atawọn ẹmẹwa rẹ lo da ẹmi ọba legbodo.
Ninu iwadii wọn, awọn agbofinro ni awọn janduku ti wọn to aadọta ni Okon ko sodi, ti wọn lọọ ṣakọlu sori ade lọjọ iṣẹlẹ yii, wọn lu ọba naa lalubami, wọn fada ati aake ṣa a yannayanna, lẹyin eyi ni wọn wọ ọ sinu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna alawọ pupa rẹ, ti nọmba rẹ jẹ APP 55 GF. Janduku kan ti wọn pe ni Agbara ni wọn lo wa ọkọ naa lọ sibi igbo ṣuuru kan lẹbaa ọna to wọ ilu Agodo, ni ọkan lara wọn ba bu bẹntiroolu si ọba naa ati ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, wọn si dana sun un.
Awọn janduku yii tun ṣakọlu si mẹta lara awọn mọlẹbi oloogbe naa, wọn lori lo ko wọn yọ ni tiwọn. Awọn mẹta ọhun ni Lydia Ọdẹtọla, Deborah Onilere, ati Alfa Wahab.
Atẹjade kan ti DSP Hauwa Laraba Idris fi lede lori ọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, sọ pe awọn afurasi tọwọ ba fẹsun kan ori ade ti wọn dana sun naa pe iṣẹ ajagungbalẹ lo n ṣe, wọn lo n fi ipo ọba rẹ awọn eeyan jẹ lati gba ilẹ wọn lọna aitọ, eyi lo mu ki wọn ditẹ mọ ọn.
Igbakeji ọga ọlọpaa patapata, AIG Adeyinka Adeleke to ṣaaju ikọ ọtẹlẹmuyẹ to n bojuto sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa.