Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ oṣelu APC ti fagi le ipade awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ naa to yẹ ko waye ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Akọwe igbimọ alamoojuto ẹgbẹ naa, John Akpanudoedehe, lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
O sọ pe, ‘‘Gẹgẹ bi Alaga apapọ alamoojuto ẹgbẹ APC, to tun jẹ Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Malan Buni, ṣe paṣẹ, ipade pajawiri awọn oloye ẹgbẹ naa to yẹ ko waye ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, ko ni i waye mọ.
Ohun ti awọn kan n sọ ni pe o ṣee se ko jẹ pe nitori bi Aarẹ Buhari ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe isakoso ẹgbẹ naa pada fun Buni lo fi kede pe ki wọn fagi le ipade ọhun, nitori oun kọ lo pe e.
Tẹ o ba gbagbe, alaga ti wọn ṣẹṣẹ yan to tun jẹ Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello ti wọn ti gba ipo naa lọwọ rẹ lo kede ipade pajawiri naa.
Ṣugbọn lẹyin lẹta ti Aarẹ Buhari kọ sawọn oloye ẹgbẹ naa lori wahala to n lọ ni wọn ni ki wọn da isakoso ẹgbẹ naa pada fun Buni.