Awọn oniṣowo gba fọọmu ogoji miliọnu Naira fun Atiku lati dije dupo aarẹ

Faith Adebọla

Afi bii ẹni pe wọn ti n reti ki ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe asiko ti wọn maa bẹrẹ si i ta fọọmu idije fawọn ipo oṣelu to maa ṣi silẹ lasiko idibo ọdun 2023, ọjọ keji, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii, tẹgbẹ oṣelu naa bẹrẹ si i ta fọọmu fawọn oludije, Atiku Abubaka, igbakeji aarẹ orileede wa laye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti gba fọọmu, oun si lẹni akọkọ ti yoo gba fọọmu aarẹ lẹgbẹ PDP.

Ẹgbẹ kan to jẹ tawọn oniṣowo iha Ariwa/Ila-Oorun ilẹ wa, North East Business Forum, eyi ti Alaaji Abubakar Dalhatu Funakaye n ṣe alaga rẹ ni awọn lawọn gba fọọmu naa fun Atiku lati ṣatilẹyin fun erongba rẹ lati dije dupo aarẹ.

Ẹgbẹ naa ni latọdun 2021 to kọja lawọn ti ṣeleri fun Alaaji Atiku Abubakar pe nigbakuugba ti anfaani ba ti ṣi silẹ lati dije, awọn lawọn maa gba fọọmu idije lati ṣe koriya fun un, awọn si ti ṣetan lati ṣe gbogbo atilẹyin lori inawo ati ifọmọniyan ṣe, ki Atiku le jawe olubori lasiko idibo.

Bakan naa ni alaga ati oludasilẹ ileeṣẹ DAAR Communications, Agba oye Raymond Dokpesi, kede pe ọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni Atiku yoo fẹnu ara rẹ kede erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023, niluu Abuja.

Dokpesi ni “A ti ṣetan lati yọ Naijiria ninu ọfin to jin si, a ti gbaradi lati koju awọn ipenija to doju kọ wa. Ọrọ eto aabo, igbaye-gbadun araalu, ọrọ awọn ọdọ ati obinrin la maa gbaju mọ ju lọ.”

Sẹnetọ Dino Melaye toun naa wa nibi iṣẹlẹ naa sọ pe awọn adigunjale taara ni wọn jale idiboyan Atiku lọdun 2021, ṣugbọn awọn araalu maa tun dibo yan an, tori wọn ṣi fọkan tan an gidi.

Nigba ti wọn mu fọọmu naa le e lọwọ, Alaaji Abubakar ni oun dupẹ gidi lọwọ awọn ọrẹ oun yii, o ni ohun ti wọn wọn ṣe jọ oun loju, tori lasiko yii, ko rọrun fawọn oniṣowo, to jẹ pe aisi ina ẹlẹntiriiki, ọwọngogo epo ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, ti ko gbogbo ere ti wọn ri lori okoowo wọn lọ, oun o si reti pe ki wọn tun wa owo rẹpẹtẹ bẹẹ lati ti oun lẹyin.

O ni oun o ni i ja wọn kulẹ.

Leave a Reply