Faith Adebọla
Niṣe ni adanu n gori adanu lasiko yii fun ọga ọlọpaa to n jẹjọ lọwọ, DCP Abba Kyari, pẹlu bi ijọba apapọ ṣe fọwọ si i pe ki wọn gbẹsẹ le gbogbo dukia ati owo ti ẹri ba fidi ẹ mulẹ pe Kyari tabi eyikeyii ninu awọn afurasi ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn fẹsun kan lo ni in.
Ninu iwe ẹbẹ kan ti ajọ to n gbogun ti okoowo ati aṣilo egboogi oloro nilẹ wa, NDLEA, gbe siwaju ijọba apapọ lọsẹ to kọja ni wọn ti bẹbẹ fun iyọnda ati aṣẹ lati gbẹsẹ le awọn dukia wọn. Ẹka eto idajọ ti Minisita feto idajọ nilẹ wa, Mallam Abubakar Malami, n dari, ni wọn kọwe naa si.
Lara awọn dukia ti wọn beere iyọnda lati gba ni ile, ilẹ, owo to wa ni banki, owo to wa lọwọ wọn, awọn otẹẹli, ile akọgbe ati akọta, awọn nnkan ẹṣọ bii aago ọwọ, ṣeeni ọrun, bata, nnkan iṣaralọṣọọ, mọto ti wọn fi n ṣẹsẹ rin ateyi ti wọn fi n ṣe okoowo, awọn irinṣẹ, atawọn nnkan iyebiye mi-in tawọn afurasi ọdaran naa n lo.
Lopin ọsẹ to kọja yii ni Malami buwọ luwe ẹbẹ naa, o ni ki wọn gbẹsẹ le gbogbo nnkan ti wọn ba ri i pe o yẹ lati gba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii laṣiiri tu pe nnkan bi biliọnu mẹrin aabọ Naira lo wa ninu akaunti ọkan ninu awọn ẹmẹwa Kyari ti wọn mu, ACP Sunday Uba, ni banki.
Lati ọjọ keje, oṣu Kẹta, ni Kyari ati awọn marun-un mi-in ti n jẹjọ lori ẹsun ṣiṣe okoowo egboogi oloro.