Idibo 2023: Awọn ọmọlẹyin Lai Mohammed darapọ mọ SDP ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn jẹ oloootọ si Minisita fun eto ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ bayii, ti wọn si ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu SDP, nipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe diẹ ninu awọn to jẹ oloootọ si minisita ọhun ni wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu SDP, bayii nigba ti awọn miiran ninu wọn n gbero lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Third Force. Aṣofin Saheed Popoola to n ṣoju ẹkun idibo Ojomu/Balogun, nijọba ibilẹ Ọffa, to lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ darapọ mọ SDP, lo kede rẹ fun awọn aṣofin ẹgbẹ ẹ lasiko ijokoo wọn n’Ilọrin, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii.

 

Leave a Reply