Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti ran tẹgbọn-taburo kan, Martins Ifebuchi, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ati aburo rẹ, John Joseph, ẹni ọdun mọkandinlogoji, sẹwọn ọdun mẹtadinlogun pẹlu iṣẹ aṣekara.
Awọn ọdaran mejeeji ti wọn jẹ ẹgbọn ati aburo yii ni awọn ọlọpaa wọ wa si ile-ẹjọ pẹlu ẹsun igbimọ-pọ ati fifi ipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan lo pọ lọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2021, ni adugbo Ajilosun, l’Ado-Ekiti, lolu ilu ipinlẹ Ekiti.
Ninu ọrọ ọmọdebinrin yii ti wọn ṣe akọsilẹ rẹ, ti wọn si ṣe afihan rẹ nile-ẹjọ naa, o ṣalaye pe Ifebuchi ati iya oun to jẹ oniṣowo ni wọn jọ jẹ ayalegbe kan naa. O ni iya oun maa n fi oun nikan silẹ sile nigba miiran, ti yoo si lọọ ra ọja niluu miiran, nibi to le lo bii ọjọ mẹta nigba mi-in ko too pada de.
O fi kun un pe Ifebuchi maa n lo anfani yii lati fipa ba oun lo pọ ti iya oun ko ba ti si nile. O fi kun un pe ni kete ti Ifebuchi ba ti ba oun lo pọ tan ni yoo sọ fun oun pe ti oun ba sọ fun iya oun, nnkan yoo ṣẹlẹ si oun.
O ni lọjọ ti aṣiri tu yii, ni kete ti Ifebuchi fipa ba oun lo pọ tan ni ọdaran keji, John Joseph, to jẹ aburo rẹ, to jẹ akẹkọọ, ṣugbọn to waa lo ọlude lọdọ ẹgbọn rẹ ri ẹgbọn rẹ to n ba oun lo pọ, loun naa ba sọ pe afi dandan ki oun ba oun lo pọ. O ni lẹyin to ba oun lo pọ tan ni ẹjẹ da si gbogbo aṣọ ori bẹẹdi iya oun.
Ọmọdebinrin yii ni iya oun lo ri ẹjẹ yii ni kete to dari de lati ọja, to si beere bo ṣe jẹ lọwọ oun, eyi lo mu koun ṣalaye fun un.
Iya ọmọ yii lo dọgbọn, to si dagbere fun Ifebuchi pe oun ti n lọ si ọja oko gẹgẹ bii iṣe oun. Ṣugbọn niṣe ni iya ọmọbinrin yii lọọ fara pamọ sibi kan. Ko pẹ sigba naa ni ọmọkunrin yii tun wọle tọ ọmọ naa lọ, nibi to ti n gbiyanju ati ka aṣọ lara rẹ nibi to sun si ni iya rẹ ti wọle ba wọn, to si gba agọ ọlọpaa lọ lati lọọ fẹjọ awọn tẹgbọn-taburo yii sun, ti ọlọpaa si pada waa ko wọn.
Agbẹjọro fun ọmọdebinrin yii, Ọgbẹni Kọla Kọlawọle, pe ẹlẹrii mẹta, o si tun mu iwe ayẹwo lati ileewosan, (medical report), wa gẹgẹ bii ẹri nile-ẹjọ naa.
Bakan naa ni agbẹjọro fun awọn ọdaran yii, Sunday Ochayi, pe ẹlẹrii marun-un, eyi ti awọn ọdaran naa jẹ meji lara wọn.
Ṣugbọn ninu igbẹjọ rẹ, Onidaajọ Adeniyi Familọni, sọ pe ẹsun ifipa ba ni lo pọ jẹ ẹsun kan pataki ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, to si le mu ifasẹyin ba igbe aye ọmọbinrin yii. Adajọ fi kun un pe yatọ si eleyii, ọjọ ori ọmọbinrin naa ṣi kere.
Adajọ ni, “Ju gbogbo rẹ lọ, awọn ọdaran mejeeji yii yẹ fun ijiya, ko le kọ ẹlomiiran lọgbọn. Awọn ọdaran mejeeji yii jẹbi ẹsun ifipa ba ni lo pọ, nidii eyi, ile-ẹjọ yii ran wọn ni ẹwọn ọdun meje lori ẹsun igbimọ-pọ, bakan naa ni wọn yoo ṣẹwọn ọdun mẹwaa ẹni kọọkan, lori ẹsun ifipa ba ni lo po.
Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, Ọtunba Sunday Ochayi to jẹ agbẹjọro fun awọn ọdaran naa sọ pe oun yoo jokoo lati gbe igbẹjọ naa yẹwo lati le pe ẹjọ ta ko o.