Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin agbẹ kan, Idowu Bayọde, lori ko yọ lọwọ awọn Fulani kan ti wọn ṣe akọlu si i ninu oko rẹ niluu Ikakumọ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi alaye ti ẹni ogoji ọdun naa ṣe fawọn oniroyin, o ni oun nikan loun lọ sinu oko laaarọ ọjọ naa lati lọọ ka awọn kaṣu to ti pọn.
O ni iyalẹnu lo jẹ foun bi oun ṣe wọnu oko ti oun si ba awọn Fulani meji nibi ti wọn ti n ka awọn kaṣu naa sinu apo nla kan to wa lọwọ wọn.
Idowu ni awọn ole naa ko ti i jẹ koun sọrọ rara ti wọn fi sun mọ oun, ti wọn si n ṣa oun ladaa ni gbogbo ara.
Bayọde ni nigba toun ṣakiyesi pe ṣe ni wọn kuku fẹẹ pa oun loun yara dibọn bii ẹni to ti ku, leyii to jẹ kawọn Fulani ọhun fi oun silẹ, ti wọn si sa lọ.
O ni igbe ti oun n ke kikan kikan lẹyin ti wọn lọ tan ni ọrẹ oun kan gbọ to fi sare wa sinu oko oun lati waa ran oun lọwọ.
Alaga ẹgbẹ ọmọ Ikakumọ, Ọgbẹni Festus Ọmọgboye, ṣalaye fun ALAROYE lori aago pe ki i ṣe igba akọkọ ree tawọn Fulani yoo ṣe akọlu si awọn eeyan agbegbe ọhun.
Ọmọgboye ni ọpọ awọn agbẹ ni wọn ko to bẹẹ lati lọọ ṣiṣẹ ninu oko wọn mọ nitori ibẹru awọn janduku darandaran.
O ni laipẹ yii lawọn Fulani ọhun kan naa ṣe akọlu kan sawọn eeyan, leyii to ṣokunfa bawọn araalu ko ṣe le na ọja mọ lati igba naa.
Ọkan ninu awọn aṣaaju ilu Ikakumọ, Ọgbẹni Foluṣọ Aminu, ni tiẹ ni ọpọ awọn ọmọ ilu to wa nilẹ okeere ni wọn ki i wale mọ nitori ọrọ ijinigbe, idigunjale ati akọlu gbogbo igba tawọn Fulani n ṣe lagbegbe Ikakumọ.
Aminu rọ ijọba lati ko ọpọlọpọ awọn ẹṣọ alaabo wa si agbegbe naa nitori aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, niwọn bo ṣe jẹ pe aala ipinlẹ Ondo ati Edo lawọn tẹdo si.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ọga ọlọpaa teṣan Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Ọlatujoye Akinwande, ni ọwọ awọn ti tẹ ẹnikan ti awọn fura si pe o lọwọ ninu rẹ.