Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Akẹkọọ kan lawọn ajinigbe ti ji gbe lọ ninu ọgba ileewe rẹ l’Akurẹ lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Iṣẹlẹ ijinigbe ọhun la gbọ pe o waye ninu ọgba ileewe girama United CAC, to wa lagbegbe Awulẹ, l’Opopona Agagu, niluu Akurẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan ti iṣẹlẹ yii ṣoju rẹ pe kilaasi keji nipele akọkọ (JSS 2) ni ọmọ ti ọn ji gbe lọ naa wa.
O ni asiko ti ọmọbinrin naa jade kuro ninu ọgba ileewe lati lọọ tọ lawọn ajinigbe ọhun sare jade nibi ti wọn sapamọ si, ti wọn si ji i gbe lọ.
Akẹkọọ kan to wa nitosi to si ri gbogbo itu tawọn ajinigbe naa pa lo sare wọ inu ọgba ileewe lati lọọ sọ ohun toju rẹ ri fawọn olukọ wọn.
Iṣẹlẹ ọhun lo ni wọn ti fi to awọn agbofinro leti lẹyẹ-o-ṣọka, ṣugbọn ko sẹni to ti i le sọ ni pato ibi tọmọ naa wọlẹ si titi di igba ta a n kọ iroyin yii lọwọ.