Ogedengbe yoo ṣẹwọn ọdun meji ataabọ, ẹni to fi mọto gba ti larun ọpọlọ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Nitori pe o wa ọkọ lai ni lansẹnsi, ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa ni Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ayọmide Ogedengbe maa lọ sẹwọn ọdun meji aabọ, pẹlu iṣẹ aṣekara.
Bakan naa ni ile-ẹjọ ko fun ọkunrin yii ni aaye lati sanwo itanran.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Ọlatọmiwa Daramọla, sọ pe agbefọba fidi ẹri to daju mulẹ, eyi to fun ile-ẹjọ naa ni aaye lati ri i pe loootọ ni ọdaran naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Onidaajọ Daramọla sọ pe ọdaran naa jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ lasiko igbẹjọ naa, o si tun kuna lati fi ẹri to daju gbera rẹ lẹsẹ.
O paṣẹ pe ki ọdaran naa maa lọ sẹwọn ọdun meji aabọ, lai si aaye sisan owo itanran.
Ogedengbe to jẹ dẹrẹba to n wa ọkọ akero lati Ado-Ekiti si Afao-Ekiti, ni wọn wọ wa sile-ẹjọ naa ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, pẹlu ẹsun pe o n wa ọkọ loju popo lai ni iwe ọkọ to daju, ati pe o n wa ọkọ niwakuwa lona ti ko ba ofin mu.
Adugbo Oshodi, loju ọna to lọ lati Ado-Ekiti si ilu Ado-Ekiti ni awọn agbofinro ti mu un ni deede agogo meji aabọ ọsan ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọjọ naa, nigba to fi ọkọ kọ lu ọmọdekunrin kan, Ojo Ige, to si da ọgbẹ si i ni gbogbo ara, eyi to fa a ti ẹjẹ fi ta si i lọpọlọ, to si n ṣe gan-an gan-an-gan lati igba naa.
Bakan naa ni Agbefọba, Insipẹkitọ Elijah Adejare, sọ pe ọdaran naa tẹ ofin kejidinlọgbọn to jẹ ofin irinna ti wọn kọ ni ipinlẹ Ekiti lọdun 2012, to si ni ijiya loju.

Lati fi idi ẹsun naa mulẹ, agbefọba pe ẹlẹrii marun-un, o si mu fọto ti wọn ya nibi ti ijamba ọkọ naa ti ṣẹlẹ silẹ. Bakan naa lo tun ko awọn iwe ti wọn fi ṣe ayẹwo ọkọ naa silẹ ati awọn ẹri miiran lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ nile-ẹjọ naa.
Agbẹjọro ọdaran naa, Ọgbẹni Ọlarewaju Oluwaṣọla, bẹ ile-ẹjọ pe ko fi oju aanu wo onibaara oun naa ti ko pe ẹlẹrii kankan.

Leave a Reply