Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Akilu Lawali ti n ṣẹju pako lahaamọ ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi bayii. Ẹsun pe o lọọ ji awọn ohun eelo ile idana lagbegbe Ayekalẹ, Ogidi, Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii ni wọn tori ẹ mu un.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ naa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lo ti sọ pe awọn eeyan Ayekalẹ, Ogidi, ilu Ilọrin, ni wọn mu Lawali lọ si olu ileeṣẹ ajọ NSCDC niluu naa, ti wọn si ni o lọọ ji awọn ohun eelo ile idana. O tẹsiwaju pe ni nnkan bii ago meje alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ọwọ tẹ afurasi ọhun, nigba ti wọn bi i leere ibi to ti ri awọn ohun eelo inu ile naa, o ni oun ra wọn lowo kekere lọwọ ẹnikan ni.
Ọmọ ijọba ibilẹ Tsafe, nipinlẹ Zamfara, ni ọmọkunrin yii pe ara rẹ, ṣugbọn o ti lo to oṣu mẹta n’Ilọrin. Niṣe ni wọn lu ọmọkunrin naa lalubami, ti wọn si ko gbogbo ẹgbẹrun meje Naira to wa lapo rẹ.
Adari ajọ ṣifu difẹnsi ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Ayinla, ti paṣẹ pe ki wọn fi i sahaamọ, ki iwadii si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa. O ni lẹyin eyi ni afurasi ọhun yoo foju ba ile-ẹjọ.