Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni kekere la ti i pẹkan iroko, to ba dagba tan, ẹbọ ni yoo maa gba. Afaimọ lọrọ eto aabo to dẹnu kọlẹ lorileede yii ko ti doriṣa akunlẹbọ sijọba lọrun bayii, pẹlu ipakupa to waye nipinlẹ Plateau, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin yii, lasiko tawọn janduku agbebọn ya bo awọn abule bii mẹwaa, nijọba ibilẹ Kanam, wọn paayan to ju ọgọrin (80) lọ, wọn ji eeyan bii aadọrin gbe, wọn dana sun ile bii aadọfa (110), ọgọọrọ lo si fara gbọgbẹ yanna-yanna.
Awọn abule wọn ti ṣe wọn bi ata ṣe n ṣoju ọhun ni Kukawa, Gyambawu, Dungur, Kyaram, Yelwa, Dadda, Wanka, Shuwaka, Dadin Kowa, ati Gwammadaji.
Wọn niṣe lawọn agbebọn afẹmiṣofo naa ja bii iji wọlu, wọn pọ bii baba eṣua lori ọkada ti wọn gbe wa, wọn mura ija gidi wa ni, bi wọn ṣe n tina bọle, bẹẹ ni wọn n yinbọn pa gbogbo ẹnikẹni to ba gbiyanju lati sa asala fẹmi ẹ, pẹlu oró ni wọn n pa wọn nipakupa.
Bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa ṣe sọ, wọn niṣe lawọn oṣiṣẹ kansu Kanam to debi iṣẹlẹ naa laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ba oku eeyan to sun bẹẹrẹbẹ, oku mejidinlogoji ni wọn ri sa jọ ni Kukawa, o si jọ pe ipakupa abule naa lo pọ ju tawọn yooku lọ.
Wọn ṣa oku mẹrinlelogun ni Gyambau, mẹwaa ni Wanna, mẹjọ ni Kyaram, awọn oku ti wọn ṣi ri laarin ilu niwọnyi, tori awọn oṣiṣẹ naa lawọn o mọye oku to maa wa lawọn igbo etile to wa kaakiri agbegbe naa.
Wọn ti ko awọn to fara pa loriṣiiriṣii lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ti Fasiti Jos (JUTH), fun itọju pajawiri.
Ẹnikan tori ko yọ lasiko akọlu buruku naa, Ọgbẹni Sariki Bitrus, sọ pe “awọn agbebọn naa ko fẹẹ ri ọkunrin eyikeyii soju rara ni, gbau gbau ni wọn ṣina ibọn bolẹ fawọn ọkunrin, wọn si n ṣa awọn obinrin jọ sẹgbẹẹ kan. O ni wọn o ṣaanu awọn ọmọde ati ọmọọwọ, niṣe ni wọn kan n yinbọn bii ẹni wa loju ogun.
“Nnkan bii aago mẹrin ku iṣẹju diẹ nidaaji ọjọ Sannde ni iṣẹlẹ naa waye, awọn eeyan diẹ ti ji lati jẹ saari, tori aawẹ Musulumi to n lọ lọwọ, ati pe awọn kan ti n palẹmọ lati bọ tete bọ sọna oko tori asiko ojo ta a wa.”
Bitrus ni o ti to ọjọ mẹta kan tawọn agbebọn ti n ṣọṣẹ nijọba ibilẹ ọhun, o ni wọn fẹẹ gba akoso igbo ọba kan to wa lagbegbe naa ni.
Awọn agbaagba ipinlẹ Plateau ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii. Akọwe iroyin ẹgbẹ wọn, Plateau Elders Forum, Ọgbẹni Jonathan Ishaku, ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Mọnde ọsẹ yii ni:
“Laarin ọsẹ kan ta a fi atẹjade lede lati bẹnu atẹ lu akọlu ati ifẹmiṣofo to waye lawọn abule Miango, nijọba ibilẹ Bassa, ati abule Rantis, nijọba ibilẹ Barkin Ladi, awọn agbebọn tun ti lọọ paayan rẹpẹtẹ nijọba ibilẹ Kanam, wọn si jiiyan bii aadọrin gbe nijọba ibilẹ Kanam lanaa.
“Iṣẹlẹ to gbomi loju eeyan leyi, o si bi wa ninu gidigidi. Awọn akọlu to n waye yii ti tubọ fidi ọrọ ta a sọ tẹlẹ mulẹ, pe kijọba ipinlẹ Plateau atawọn oṣiṣẹ alaabo fọwọ dan-in dan-in mu ọrọ aabo ilu ju bi wọn ṣe n ṣe tẹlẹ lọ.
“A ba awọn to ṣofo ẹmi ati dukia ninu akọlu yii kẹdun, a si gbadura ki Ọlọrun jẹ kawọn to fara gbọgbẹ tete gbadun.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau, ASP Gabriel Ubah, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O loun o le sọ pato iye eeyan to ṣofo ẹmi ninu akọlu ọhun, tori iwadii ṣi n lọ lori ẹ. O lawọn ti ko ọlọpaa rẹpẹtẹ lọ sawọn agbegbe naa.