Adewumi Adegoke
Lati sami ayẹyẹ ọdun Ajinde, ijọba apapọ ti kede ọjọ kẹẹẹdogun ati ikejidinlogun, oṣu Kẹrin yii gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Minisita fun ọrọ abẹle nilẹ wa, Rauf Aregbẹṣọla lo kede ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede lati ọwọ akọwe agba fun ileesẹ naa, Dokita Shualib Belgore, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Abuja.
O rọ awọn onigbagbọ lati fi iwa Jesu gẹgẹ bii ẹni to fi ara rẹ ji, to dariji, to ni aanu ifẹ, ipamọra ati iwapẹlẹ ṣe awokọṣe.
Bakan naa lo sọ pe gbogbo ohun to ba wa ni ikapa ijọba apapọ ni wọn yoo ṣe lati ri i pe wahala to n ṣelẹ lori eto aabo dopin
O fi kunun pe ojuṣe gbogbo araalu ni ọrọ eto aabo jẹ. Bẹẹ lo rọ tolori-telẹmu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori eto aabo nilẹ wa.