Ọlawale Ajao, Ibadan
Lati ṣe gbogbo etutu to yẹ lori iku ọba nla to waja nilẹ Yoruba, wọn ti laago kaakiri ilu Ọyọ pe isede yoo wa lati aago mẹjọ alẹ ọjọ Abamẹta di ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde.
Deede aago mẹsan-an alẹ ni wọn yoo gbe oku Ọlayiwọla Adeyẹmi lọ si Baara, niluu Ọyọ yii kan naa, nibi ti wọn yoo ti sin ọba naa si ibi ti wọn n sin awọn Alaafin ti wọn ti jẹ niluu Ọyọ ṣaaju si.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin yii, ni Ọlayiwọla Adeyẹmi waja.