Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo ti sun igbẹjọ lori iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, to ku sinu otẹẹli Hilton, niluu Ileefẹ, loṣu Kọkanla, ọdun to kọja, siwaju di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Dokita Rahmọn Adedoyin to ni otẹẹli naa loun ati awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa n jẹjọ lori iku Adegoke. Wọn kọkọ ko wọn lọ si Abuja, ko too di pe wọn da ẹjọ naa pada sipinlẹ Ọṣun, ti igbẹjọ naa si bẹrẹ nile-ẹjọ giga niluu Oṣogbo loṣu Kẹta, ọdun yii.
Nigba ti wọn fara han nile-ẹjọ gbẹyin, Onidaajọ Adepele Ojo dajọ lori ohun ti awọn agbẹjọro olujẹjọ gbe siwaju rẹ pe awọn onibaara awọn ko lẹjọ lati jẹ.
Adepele Ojo sọ pe lọna kan tabi omi-in, ọkọọkan awọn olujẹjọ ni nnkan kan an ṣe pẹlu ẹsun ti wọn fi kan wọn lori ọrọ iku Adegoke, nitori naa, ki wọn bẹrẹ awijare wọn lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Ọṣun, nipasẹ Kọmiṣanna feto idajọ, Fẹmi Akande, ti fun ọfiisi Agbẹjọro Agba, Fẹmi Falana, lagbara lati maa ba igbẹjọ naa lọ latari lẹta ti Falana kọ ati bi awọn mọlẹbi Adegoke ṣe fẹ ẹ.
Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lẹyin ti awọn agbẹjọro ti kede orukọ awọn ti wọn n ṣoju fun ni agbẹjọro kan lati ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun, Barisita Badiora, kede pe oun ati ẹnikeji oun, Farẹmi, wa lati ṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun.
Ọrọ yii lo fa ariyanjiyan laarin awọn agbẹjọro olujẹjọ ati Fẹmi Falana (SAN). Agbẹjọro agba Ẹlẹja, Agbẹjọro agba Muritala Rasheed ati Agbẹjọro Edet, wọn sọ pe Falana ko tẹle ilana to tọ lati gba ẹjọ naa lọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun.
Wọn ni latigba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ, ko si ọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun nibẹ rara. Ijọba apapọ, nipasẹ ileeṣẹ ọlọpaa, ni wọn n ṣe e, bawo waa ni agbara lori ẹjọ naa ṣe fo latọdọ ọlọpaa sọdọ ijọba ipinlẹ Ọṣun, tipinlẹ Ọṣun naa fi wa n fun ẹnikan lagbara?
Ṣugbọn Falana sọ ninu awijare tirẹ pe ninu ofin, ko si asiko kan ni pato tijọba ipinlẹ le gba igbẹjọ lori ẹjọ to ba ṣẹlẹ lakata rẹ lọwọ ọlọpaa, ko si pọn dandan ki wọn kọkọ kọ iwe sita lati gba a. Amọ ṣa, oun yoo fara mọ ohun ti awọn agbẹjọro olujẹjọ n beere nitori ọgbọn ko pin sibi kan.
Eleyii ni wọn n fa lọwọ ti olujẹjọ keji, Magdalene, fi bẹrẹ si i hukọ leralera, nigba ti ko le naro daadaa mọ lo bẹrẹ mọlẹ, bi awọn agbẹjọro si ṣe fi to adajọ leti ni iyẹn sọ pe ki igbẹjọ duro diẹ naa, bẹẹ lo wọle lọ.
Lẹyin iṣẹju marun-un to pada de, gbogbo wọn fẹnu ko lati bẹrẹ igbẹjọ. Agbẹjọro to duro fun Adedoyin, Ẹlẹja (SAN), lo kọkọ sọrọ. O ni lẹyin ti oun ṣayẹwo gbogbo ẹri ti awọn olupẹjọ gbe siwaju kootu, oun pinnu pe onibaara oun ko ni ẹlẹrii kankan lati pe.
Agbẹjọro agba, Muritala Muhammed, to n ṣoju fun olujẹjọ keji, ikẹrin ati ikarun-un, sọ pe yatọ si pe ara olujẹjọ keji ko ya, oun ko tun raaye lati kiyesi iwe ẹjọ naa latari bi oun ṣe nidiwọ nipa irinajo oju ofurufu oun fun wakati marun-un lọjọ Sannde.
Nitori naa, o rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju digba ti Magdalene yoo fi gbadun daadaa, ti oun naa yoo si fi raaye gbaradi fun igbẹjọ naa.
Muhammed naa lo ṣoju fun Agbẹjọro agba, Otaru, to n duro fun awọn olujẹjọ kẹta ati ikẹfa. Ohun kan naa lo beere fun.
Ni ti Agbẹjọro Edet to n duro fun olujẹjọ keje, o ni onibaara oun ti ṣetan lati pe ẹlẹri meji lori igbẹjọ naa, ṣugbọn niwọn igba ti awọn olujẹjọ mẹfa akọọkọ ko ti i ṣetan, oun naa rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju.
Niwọn igba ti Falana ko ti tako ibeere awọn agbẹjọro to ku, Onidajọ Adepele Ojo sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un ọdun yii.