Ọlawale Ajao, Ibadan
Idris Abọlaji Abiọla-Ajimọbi, ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, naa ti fifẹ han lati dupo aṣofin ipinlẹ Ọyọ ninu idibo ọdun 2023 to n bọ yii.
Nigba to n kede ipinnu rẹ fawọn adari ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ (APC), nijọba ibilẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Idris, to jẹ akọṣẹmọṣẹ oluṣiro owo, sọ pe oun ti ṣetan lati dupo aṣofin ti yoo ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Guusu Ibadan Keji nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lasiko idibo to n bọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ọjọ oni jẹ ọjọ manigbagbe fun emi ati idile mi pẹlu awọn eeyan ẹkun idibo Iwọ-Oorun Guusu Ibadan Keji. Idi ni pe oni yii ni mo kede ipinnu mi lati dupo aṣofin ti yoo ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Guusu Ibadan Keji nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lasiko idibo to n bọ, nitori o pẹ ti erongba yẹn ti wa lọkan mi pe emi naa maa ṣiṣẹ sin awọn araalu lọjọ iwaju.
“Mo mọ pe gbogbo ẹyin tẹ ẹ wa nibi lẹ mọ baba mi, ẹ mọ ipa rere ti wọn fi lelẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ yii. Ẹ si mọ ipa ti baba wọn naa, baba mi agba, Oloogbe Ganiyu Ajimọbi, fi lelẹ nigba ti awọn naa fi jẹ aṣofin to ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Guusu Ibadan Keji yii lasiko iṣejọba Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ.
“A ko gbọdọ jẹ ki awọn ipa rere tí awọn baba mi wọnyi fi silẹ parẹ. Idi niyi ti mo ṣe duro siwaju yin lonii lati beere fun atilẹyin yin, ki n le ṣaṣeyọri lati di aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo yii nitori mi o le da iṣẹ naa ṣe.”
Ta o ba gbagbe, baba ọkunrin to fẹẹ dupo aṣofin yii, Oloogbe Isiaq Abiọla Ajimọbi, lo ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ laarin ọdun 2011 si 2019, to tun dupo sẹnetọ lati lọọ ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ niluu Abuja, ṣugbọn to fidi-rẹmi ninu idibo ọhun to waye lọdun 2019.