Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gẹgẹ bo ṣe ṣe fun olori ti tẹlẹ, Channel Chin, Oluwoo ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, tun ti de ade fun olori tuntun, Firdauz Akanbi.
Ninu ọrọ ti kabiesi fi sori ikanni ayelujara, Oluwoo ni gbogbo olori lo lẹtọọ si ade.
O ni awọn baba nla oun Oduduwa lo kọ oun lẹkọọ lati fẹran Olori, ki oun si de e lade, idi niyẹn ti Oduduwa fi de iyawo rẹ, Olokun lade.