Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari iyanṣẹlodi ti awọn olukọ fasiti kaakiri orileede yii, Academic Staff Union of Nigerian Universities (ASUU), gun le lati ọpọ oṣu sẹyin, awọn akẹkọọ Fasiti Ifẹ fẹhonu han.
Wọn n binu lori bijọba apapọ ṣe kuna lati dahun si ibeere awọn olukọ naa, eleyii to mu ki wọn maa woṣẹ niran, to si n ṣakoba fun eto ẹkọ lorileede yii.
Aarọ lawọn akẹkọọ naa ti kọkọ pejọ siwaju geeti ileewe wọn, latibẹ ni wọn ti n fẹhonu han kaakiri awọn agbegbe bii Mayfair, Damico, Urban Day, ti awọn kan si di oju-ọna to n bọ lati Ibadan si Ifẹ ati eyi to n lọ si Ibadan lati Ifẹ.
Gbogbo awọn bọọsi akero atawọn ọlọkada ni wọn ko jẹ ki wọn ṣiṣẹ, ti wọn si n pariwo pe diduro nile ti su awọn, afi kijọba apapọ tete wa nnkan ṣe lori ọrọ naa.
Oniruuru akọle ni wọn gbe dani, lara awọn nnkan ti wọn si kọ sara awọn akọle naa ni pe “Ẹ ya owo to pọ sọtọ fun eto ẹkọ”, “Ijọba apapọ Naijiria ti ja awa akẹkọọ kulẹ”, “O ti to akoko bayii kijọba dahun si ibeere awọn olukọ fasiti”, “Eto ẹkọ wa ti n dẹnu kọlẹ” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni wọn ke si awọn olukọ fasiti kaakiri orileede yii naa lati joko papọ
pẹlu ijọba apapọ, ki wọn si fi ẹnu ko lori ohun ti wọn n beere, ki awọ le pada si kilaasi kiakia.