Ṣeun to gun ale rẹ lọbẹ l’Ondo ni oun fi daabobo ara oun ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Ṣeun Ṣọla ti ṣalaye idi to fi gun ale rẹ, Lomi Akinbinu, lọbẹ lasiko ija ajakuata kan to waye laarin wọn nile to n gbe niluu Ondo laarin ọsẹ to kọja.
Ninu alaye ti Ṣeun ṣe lo ti sọ pe Lomi ti kọkọ wa sile oun to wa lagbegbe Iya Laje, lọsan-an ọjọ naa, to si fun awọn ibeji oun ni ẹẹdẹgbẹta Naira nigba to fẹẹ maa lọ.
Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ lo ni ọmọkunrin ọhun tun pada wa, to si ni oun fẹẹ sun sile oun, ṣugbọn ti oun kọ jalẹ fun un lati ṣe bẹẹ.
Obinrin to n ṣiṣẹ ounjẹ tita ọhun ni esi ti oun fun Lomi lo mu ko fibinu beere owo to fun awọn ọmọ oun lọsan-an, eyi ti oun da pada fun un loju-ẹsẹ ko le tete maa ko wahala rẹ lọ.
Ṣeun ni oun mọ pe lara ohun to bi ale oun tẹlẹ ọhun naa ninu ni ti ọkunrin mi-in to ba lọdọ oun lalẹ ọjọ naa, dipo ti iba si fi maa lọ lẹyin to gba ẹẹdẹgbẹta Naira rẹ pada tan, o ni ẹsẹ lo yọ ti oun to si n lu oun ni ẹni maa ku.
O ni nigba ti ẹmi oun fẹẹ bọ lọwọ rẹ loun fa ọbẹ yọ si i lati fi gbeja ara oun.
Gẹgẹ ba a tun ṣe fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọlọpaa kan to mọ nipa iṣẹlẹ naa daadaa, Lomi ni wọn lo ta ku wọnnle pe afi dandan ki ale tuntun ti ololufẹ rẹ atijọ ọhun ṣẹṣẹ n yan lọrẹẹ kuro ki oun naa too lọ.

Ohun to fa ariyanjiyan laarin awọn mejeeji ki esu too ba wọn ta epo si i, to waa di nnkan ti wọn n lu ara wọn ni alubami, eyi to ṣokunfa bi Iya Ibeji ṣe binu fa ọbẹ yọ lati fi gba ara rẹ silẹ.
Awọn eeyan kan lo ni Ọlọrun lo lati doola ẹmi Lomi pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e lọ silẹ-iwosan ijọba to wa loju ọna Laje, l’Ondo, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni wọn wọ Ṣeun lọ sile-ẹjọ Majisreeti kan to wa niluu Ondo, nibi ti wọn ti fi ẹsun ṣiṣe eeyan leṣe lọna aitọ kan an.
Agbefọba, Benard Ọlagbayi, ni ọmọbinrin ọhun ti ṣẹ sofin ojilelọọọdunrun din meji (388), ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Lẹyin atotonu diẹ lati ẹnu Ọgbẹni P. O. Afọlayan to jẹ agbẹjọro rẹ, Onidaajọ Charity Adeyanju ni oun gba ki wọn gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira.
Ogbọnjọ oṣu Karun-un, ọdun ta a wa yii, ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply