Faith Adebọla
Igbakeji aarẹ orileede wa tẹlẹ, to tun jẹ ondije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Alaaji Atiku Abubakar ti ṣeleri pe ti oun ba fi le de ipo aarẹ orileede yii lọdun 2023, ko ni i sẹni to maa ji kọbọ kan owo ijọba ko sapo ara ẹ, tori oun o ni i gba iru ẹ laaye rara ni toun ni.
Satide, Abamẹta, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un yii, ni Atiku fọwọ ọrọ naa gbaya niwaju awọn aṣoju ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Rivers, lasiko abẹwo ati ifikunlukun rẹ sọdọ wọn.
Atiku ni ọwọ dain-dain loun maa fi mu eto ẹkọ, ko si ni i si iru iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ bii eyi to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ yii, ati pe atunto maa de ba iṣejọba orileede yii lasiko toun.
O bẹnu atẹ lu iṣakoso to wa lori aleefa bayii, o ni ijọba Buhari ti jẹ kawọn onṣejọba rẹ dari owo to yẹ ki wọn na lori eto ẹkọ sinu apo ara wọn, niṣe ni wọn n ji owo ko, eyi lo si fa a ti eto ẹkọ fi dẹnu kọlẹ.
“Ma a ri i daju pe a mojuto eto ẹkọ wa daadaa bo ṣe yẹ. Lonii, gbogbo fasiti ijọba ni wọn ti tilẹkun pa fun ọpọ oṣu bayii, awọn ọmọ wa o ri ileewe lọ, ki i ṣe pe a o fi ilana ti awọn fasiti wọnyi yoo fi maa ri owo na lelẹ lasiko ti PDP ṣejọba sẹyin o, ṣugbọn nitori jiji ti wọn n ji owo naa ko ni, ikowojẹ ni koto ọba lo pọ ju. Ma a ri i daju pe ko sẹnikẹni to maa ji owo ilu ko lasiko temi, mo bura fun yin, mi o ṣawada.”
“Ta a ba ti yanju ti eto ẹkọ, ti iyẹn ba ti duro, a maa waa wo ọrọ atunto orileede yii. O pọn dandan lati da gbogbo ohun to wọ pada si bo ṣe yẹ.”
Atiku tun sọko ọrọ sijọba to wa lode yii, o ni wọn ti da ọta silẹ laarin awọn ọmọ orileede yii gidigidi, ẹbi wọn si ni iṣoro eto aabo to fẹju kẹkẹ lasiko yii. O ni oke ni Buhari ba Naijiria lọdun 2015 to gori aleefa, ṣugbọn niṣe lo re orileede naa lẹpa, to si ja a wa sisalẹ patapata, ṣugbọn oun ti ṣetan lati tun fa a goke pada.
“Ṣe eeyan le ṣakoso lai si irẹpọ ati alaafia laarin awọn araalu ni? Eyi ṣe pataki gidi. Lasiko yii, tori ijọba bamubamu ni mo yo ti ẹgbẹ APC n ṣe, ti wọn o bikita fẹlomi-in, aisi iṣọkan ati iyapa lo gbode. Idi niyẹn ti mo fi sọ ninu ọrọ akọsọ mi nigba ti mo gba fọọmu idije pe ohun akọkọ ti ma a ṣiṣẹ le lori ni iṣọkan, alaafia ati irẹpọ.” Bẹẹ ni Atiku wi.