Abiru ki waa leleyii, baale ile lu iyawo ẹ pa n’lọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni iwadii ṣi n lọ lori ọrọ baale ile kan to jẹ ọmọ Aafa Kọrọ, lagbegbe Oke-Apomu, niluu Ilọrin, to lu iyawo rẹ lalubami titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.
Awọn to sọrọ naa fun ALAROYE ṣalaye pe ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee to lọ yii, ni ede aiyede bẹ silẹ laarin obinrin naa, Alaaja Iyabọ, ati ọkọ rẹ, Aafa, ti wọn pe ni ọmọ Aafa Kọrọ, latari ọrọ ti ko to nnkan.
Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe gbogbo igba ni ọkunrin yii maa n lu iyawo rẹ ti ija kekere ba ti ṣẹlẹ laarin wọn. Iru rẹ lo si ṣẹlẹ lọjọ Ẹti yii. Wọn ni ọmọ agboole kan ti wọn n pe ni ile Jẹjẹ, lagbegbe Okekere, niluu Ilọrin, iyawo ti ọkọ rẹ lu pa yii ti wa.
A gbọ pe lẹyin to lu iyawo rẹ lalubami tan tiyẹn n pọkaka iku ni ọkọ rẹ sare gbe e lọ si ileewọsan, ṣugbọn wọn ko ri ẹmi rẹ du, nitori o pada jade laye.
W ọn ti sin oku rẹ ni ilana ẹṣin Musulumi.

Leave a Reply