Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aarẹ agbarijọpọ ẹgbẹ onigbagbọ, Pentecostal Fellowship of Nigeria (PFN), Biṣọọbu Francis Wale Oke, ti sọ gbangba pe ẹgbẹ naa ko ni i ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kankan to ba gbe oludije ti aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin Musulumi kalẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023.
Biṣọọbu Oke sọrọ yii nibi ayẹyẹ ọgbọn ọdun ti wọn ti da PFN silẹ, eyi to waye niluu Oṣogbo. O ni orileede to fẹju, to si ni oriṣiiriṣii ẹsin ni, nitori naa, awọn Krisitiani ko ni i kawọ gbera, ki aarẹ orileede Naijiria ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin Musulumi.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin wọn nipinlẹ Ọṣun, Bisọọbu Ṣeun Adeoye, fi sita ni Oke ti ṣalaye pe oun ti ko bojumu ni, ki ẹnikẹni to jẹ Musulumi tun maa gbero lati gba’po lọwọ Muhammadu Buhari lẹyin to ti lo ọdun mẹjọ lori aleefa.
O ni awọn Onigbagbọ kaakiri orileede yii ti wọn wa labẹ PFN to miliọnu lọna marundinlaaadọrun-un, awọn yoo si ṣe itaniji fun wọn lati ma ṣe dibo fun ẹgbẹ oṣelu to ba dan iru rẹ wo.
Oke fi kun ọrọ rẹ pe, “Ọbasanjọ gbe ipo fun Yaradua, Yaradua gbe e fun Jonathan, Jonathan gbe e fun Buhari, ta lo waa yẹ ki Buhari gbe eeku ida le lọwọ bi ko ṣe Krisitiani?
O wa ke si gbogbo awọn Onigbagbọ ti wọn wa labẹ PFN lati lọọ gba kaadi idibo wọn, ki wọn si ri i pe awọn fi ibo le ijọba ti ko ba wulo lọ.
Lori bi awọn kan ṣe ṣeku pa Deborah Samuel niluu Sokoto, Bisọọbu Oke bu ẹnu atẹ lu iwa naa. O ni ipaniyan nitori ẹsin jẹ iwa aiṣododo ati iwa to lodi si ofin Ọlọrun, o si yẹ ki opin de ba iru iwa bẹẹ lorileede Naijiria.
O rọ awọn adari ẹsin lorileede yii lati ba awọn ọmọlẹyin wọn sọrọ. O ni iwa ọdaran ni ipaniyan jẹ, ijọba si gbọdọ wa awọn ti wọn huwa naa jade lati fi iya to tọ jẹ wọn.