Ọrẹoluwa Adedeji
Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti fi ọjọ mẹfa kan kun gbedeke ọjọ ti wọn fun awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri ilẹ wa lati ṣeto idibo abẹle wọn, ki wọn si fa oludije kalẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni wọn sọ eyi di mimọ lẹyin arọwa ti Alaga igbimọ akojọpọ ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun ti wọn forukọ silẹ lọdọ ajọ naa ti wọn pe ara wọn ni Inter-Party Advisory Council (IPAC), Yagabi Sani, ṣe, nibi ti wọn ti bẹbẹ pe ki wọn fun wọn ni ọjọ diẹ si i. Wọn rọ ajọ eleto idibo lati jẹ ki awọn ṣe amulo ọjọ to wa laarin ọjọ kẹta si ikẹwaa, oṣu Kẹfa yii, ti ko fi bẹẹ si ohunkohun lati ṣe ju ki wọn maa fi orukọ awọn oludije wọn ranṣẹ sori ẹrọ kọmputa INEC lọ.
Lẹyin ibeere yii ni Alaga INEC,Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ṣepade pẹu awọn ẹgbẹ oṣelu yii, bẹẹ lo ṣepade pẹlu awọn igbimọ tiẹ naa. Lẹyin eleyii lo gba ipẹ akojọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu yii, to si fi ọjọ mẹfa kan kun ọjọ ti wọn yoo pari ohun gbogbo to ba jẹ mọ eto idibo abẹle wọn.
Pẹlu ayipada yii, ko pọn dandan ki awọn ẹgbẹ oṣelu yii pari eto idibo abẹle wọn ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, gẹgẹ bi wọn ṣe fun wọn ni gbedeke tẹlẹ, ni bayii, wọn ni anfaani si i lati fi ṣeto gbogbo ti wọn ba fẹẹ ṣe titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa.
Ṣaaju ni awọn ẹgbẹ oṣelu yii ti kọkọ rọ ajọ eleto idibo lati fi ọjọ mẹtadinlogoji si ọgọta (37-60) kun ọjọ idibo abẹle naa, ṣugbọn INEC yari pe ko sohun to jọ ọ nitori pe yoo ṣakoba fun eto idibo ọdun to n bọ.