Ọlawale Ajao, Ibadan
Sẹnetọ Teslim Fọlarin lo jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC.
Fọlarin, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja lọwọlọwọ, lo la alatako rẹ to sun mọ ọn ju lọ ninu idije naa mọle pẹlu ibo ojilelẹẹẹdẹgbẹrun ati marun-un (945).
Oloye Adebayọ Adelabu, ẹni to bori ninu irufẹ idibo yii lọdun 2019, to si dupo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, lo ṣe ipo keji ninu idije naa pẹlu ibo okoolelọọọdunrun ati meje (327).
Akeem Agbaje lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo mẹẹẹdogun, Hakeem Alao to ṣe ipo kẹrin ni ibo mẹfa, nigba ti Amofin-Agba Niyi Akintọla ko ni ibo kankan ni tiẹ.
Ninu awọn oludije mẹfẹẹfa, Oloye Adelabu ati Amofin Akintọla nikan ni wọn ko yọju sibudo idibo. Adelabu lọ lọjọ Tọsidee ni tiẹ, nigba ti Amofin Akintọla ko yọju sibẹ rara.
Sẹnetọ Tokunbọ Afikuyọmi lo lewaju igbimọ ẹlẹni marun-un to ṣakoso idibo ọhun to waye ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ, laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2022 yii.
Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, lo yẹ ki eto idibo ọhun waye, ṣugbọn igbimọ alakooso eto yii sun un siwaju di ọjọ keji, nitori ti eto aabo ko daju to pẹlu bi awọn ti ki i ṣe oludibo ṣe pọ rẹpẹtẹ nibudo idibo naa.
Niṣe leto aabo duro gbọingbọn titi ti eto idibo ọhun fi pari pẹlu bo ṣe jẹ pe CP Ngozi Onadeko ti i ṣe oga agba awọn olopaa ipinlẹ Ọyọ funra ẹ lo ko ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọlọpaa sodi lati pese aabo to munadoko fun aṣeyọri eto yii. Awọn eleto aabo yooku bii NSCDC (sifu difẹnsi), Amọtẹkun ati OPC ko si da awọn ọlọpaa da iṣẹ ọhun.
Ninu ọrọ to sọ ni kete ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo ọdun 2023, Fọlarin, ẹni to fi idunnu ẹ han si iṣẹlẹ yii, dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ẹ pẹlu gbogbo ọmọ ẹgbẹ to kopa ninu idibo naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “APC ti jawe olubori, ijọba awa-ara-wa ti jawe olubori’.
Bẹẹ lo fi igbagbọ ẹ han pe ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ ni yoo tẹwọ gba iṣakoso ijọba ipinlẹ ọhun lẹyin idibo gbogboogbo ọdun to n bọ.
Ṣugbọn ọjọ keji ti wọn wọn dibo naa tan ni ALAROYE gbọ pe Adelabu ti n mura lati gba ẹgbẹ oṣelu SDP lọ lati lọọ dije dupo gomina lẹyin to fidi rẹmi ninu ẹgbẹ APC.
Ọkọ ninu awọn alatilẹyin rẹ to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe eto idibo abẹle naa ni ọwọ kan eru ninu, latari eyi, ko sohun to buru bi ọga awọn ba lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mi-in lati dan agbara rẹ wo. Bẹẹ lo ṣeleri pe gbogbo awọn lawọn maa tẹle e lọ sinu ẹgbẹ yoowu to ba n lọ.