Korede n jale ni Magodo, Yahaya n ja tiẹ lori biriiji Ọtẹdọla, ọwọ ti tẹ wọn

Faith Adebọla, Eko

Ọwọ awọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squad) ti tẹ awọn afurasi adigunjale meji kan, Korede Saheed, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ati Yahaya Faisal, ẹni ọdun mejilelogun pere, ẹsun ole jija nirona ni wọn fi kan wọn, ti wọn fi mu wọn.

Korede ni wọn kọkọ mu, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu Karun-un taa wa yii lọwọ ba oun ni ẹsiteei Magodo, nibi to ti n ja baagi ati foonu awọn ero to n lọ to n bọ gba, ọjọ keji, ọjọ Furaidee ni Yahaya ko sakolo wọn ni tiẹ, ori biriiji Ọtẹdọla ni wọn loun ti n ṣọṣẹ fawọn onimọto atawọn to n fẹsẹ rin lagbegbe naa.

Ẹnikan ti wọn ja lole lọjọ Tọsidee ọhun lo ta awọn ọlọpaa RRS lolobo, lasiko ti wọn n ṣe patiroolu wọn kiri, ni wọn ba le Korede mu. Nigba tọwọ tẹ ẹ, ti wọn yẹ ara ẹ wo, wọn ba foonu oriṣiiriṣii lara ẹ.

Korede yii lo ṣamọna bi wọn ṣe ri Yahaya mu, nigba ti wọn tu ara awọn mejeeji wo, ọkanjua ki i jale wẹwẹ, awọn foonu olowo nla bii Samsung Galaxy S8 ati iPhone mejila ni wọn ba lara wọn.

Wọn tun ka oriṣiiriṣii kaadi ti wọn fi n gbowo lẹnu ẹrọ ATM lara Yahaya, orukọ ẹ si kọ lo wa lara awọn kaadi naa, lo ba jẹwọ pe ọwọ awọn eeyan to ko si pampẹ oun loun ti ri i. O tun ṣalaye pe oun atawọn ẹmẹwa oun lawọn n da awọn ero lọna lagbegbe Ojodu si Berger, titi de biriiji Ọtẹdọla.

Ṣa, iṣẹ iwadii ti n tẹsiwaju lori awọn alọ-kolohun-kigbe ẹda yii, gẹgẹ bi Ọga agba ikọ RRS, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ṣe sọ ninu atẹjade kan, o ni wọn ti taari wọn si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n tọpinpin lati ṣewadii kunnakunna, ibẹ si ni wọn maa gba dele-ẹjọ laipẹ, ati pe gbogbo awọn to sa lọ ninu awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹẹbi ọhun lawọn maa tọpasẹ wọn lati mu wọn, gẹgẹ bii Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Abiọdun Alabi, ṣe paṣẹ.

Leave a Reply