Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe nnkan ibanujẹ nla ni bi iyapa ati ipinya nla ṣe wa laarin awọn adari oṣelu ilẹ Yoruba lasiko yii ti idibo apapọ ku si dẹdẹ.
Ọba Akanbi ṣalaye pe o ya oun lẹnu pupọ bi ko ṣe si iṣọkan laarin awọn aṣaaju ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lorileede Naijiria, to waa jẹ pe ilu konkojabele lonikaluuku wọn n lu.
Oluwoo, ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, ke si aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, Bola Ahmed Tinubu, Oloye Bisi Akande, Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, awọn to ti ṣe gomina ilẹ Yoruba sẹyin atawọn ti wọn wa nibẹ lọwọlọwọ lati mọ pe iran Yoruba ko ni i dariji wọn ti anfaani nla yii ba bọ mọ wọn lọwọ lọdun 2023.
Ọba Akanbi parọwa si Aṣiwaju Bọla Tinubu lati ṣa gbogbo ipa rẹ lati ṣatunto ẹgbẹ oṣelu rẹ fun anfaani iran Yoruba lapapọ.
O ni, “Mimu isọkan wa laarin awọn oloṣelu iran Yoruba ninu ẹgbẹ APC ṣee ṣe ti onikaluku ba le bọ agbada igberaga silẹ. Asiko ti a wa yii jẹ eyi to ṣe pataki pupọ nilẹ Yoruba.
“Gẹgẹ bii baba, ominu n kọ mi pupọ. Awọn gbajumọ ilẹ Yoruba ati awọn ẹgbẹ to ni nnkan an ṣe pẹlu oṣelu nilẹ yii gbọdọ ji giri. Mo rọ Aṣiwaju Tinubu lati ṣe bii baba to maa n ṣe, lati gba iran Yoruba lasiko yii.
“A ko gbọdọ ṣe aṣiṣe miiran. Anfaani bantabanta la ni yii. Ti Yoruba ba padanu anfaani yii lọdun 2023, o maa ni nnkan an ṣe lori ọjọọwaju wa ninu oṣelu.
“Agba ki i wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ. Mo woye pe ki awọn ọmọ Yoruba lọ si idibo komẹsẹ-o-yọ ti ẹgbẹ APC da bii fifọwọ lẹran ki ọmọ ẹni rinhooho lọ sọja.
“Mo gbagbọ pe ko ti i pẹ ju lati ṣe atunṣe to yẹ bayii. Ile to ba yapa siraa wọn yoo wo ni. Pupọ awọn ti wọn jade ninu ẹgbẹ APC bayii jẹ ọmọ abẹ orule kan naa, wọn le forikori, fikunlukun, ki wọn gbaruku ti oludije kan ṣoṣo.” Oluwo lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.