Nitori ọrọ iwe-ẹri rẹ, ọmọ ẹgbẹ APC kan ni ki wọn yọ orukọ Tinubu kuro lara awọn oludije

Mosunmọla Saka
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan nipinlẹ Kano, Sagir Mai Iyali, ti kọwe ẹsun ta ko oludije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ wọn, Bọla Tinubu, pe ki awọn igbimọ ti Oyegun jẹ adari fun wọn yọ ọ kuro laarin awọn oludije ṣaaju ibo abẹle.
Ninu lẹta ti Iyali kọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, lo ti beere fun yiyọ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri ọhun lori awọn iwe-ẹri kan to loun ni.
O tun ṣalaye pe awọn iwe ofege ni Tinubu ko siwaju awọn igbimọ eleto idibo INEC, lọdun 1998.
Iyali tẹsiwaju pe Tinubu ti dagba tayọ ẹni to yẹ ko dupo aarẹ, nitori ko sẹni to mọ ọjọ ori rẹ, fun idi eyi, awọn iwa aisododo Tinubu lori ọrọ ipo aarẹ to fẹẹ du yii le ṣe akoba nla fun ẹgbẹ naa lakooko idibo.
Ninu ọrọ ẹ, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ẹsun ọhun, Iyali sọ pe, “A mọ daju pe Bọla Tinubu to ti fi erongba rẹ han lati dupo, to si tun ti gbe fọọmu to ra siwaju awọn igbimọ tọrọ kan ni awọn ọrọ kan nilẹ to le mu ki wọn fagi le ọrọ ipo to n du.
“Ta a ba ti ibi awọn iwe ti Tinubu ko siwaju ajọ eleto idibo INEC wo o, paapaa ju lọ ti ọdun 1999, irọ banta ni Ọgbẹni Tinubu pa sinu ibura, nigba to sọ pe ileewe giga University of Chicago loun ti kẹkọọ gboye laarin ọdun 1972 si 1976.
“O ti waa han gbangba gbàǹgbà pe irọ to jinna si ootọ ni awọn nnkan ti Tinubu sọ yii. Ki i ṣe inu iwe to gbe siwaju ajọ INEC logunjọ, oṣu Kejila, ọdun 1999 nikan, bẹẹ naa lo ṣe wa ninu iwe ibura ti Tinubu ṣe niwaju ile-ẹjọ giga ilu Eko, eyi to fikalẹ si Ikẹja, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 1998”.
Ninu iwe ẹsun yii ni wọn ti ni ki Tinubu wa awọn ẹri lati fihan pe loootọ ati lododo lo kawe nileewe giga Fasiti Chicago tabi ki awọn igbimọ pa a laṣẹ pe ki wọn yọ ọ, ko si padanu ipo to n du gẹgẹ bi iwe ẹri to n parọ pe oun gba nileewe giga ọhun ṣe wa lakata awọn ẹgbẹ alatako.
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ, Iyali tun ni, “Lati aimọye ọdun, a ko mọ iru eeyan ti Aṣiwaju Bọla Tinubu jẹ. Koda, ko sẹni to le sọ pe oun mọ ọkunrin naa daadaa. Gbogbo akitiyan, ibeere ati iwadii awọn araalu atawọn oniroyin lati ṣawari iru eniyan ti Tinubu jẹ lo ti ja si pabo”.

Lasiko to n fesi si iwe ẹsun ti wọn ta ko ọga ẹ, oluranlọwọ Tinubu lori eto iroyin, Tunde Ramon, sọ lọjọ Aje, Mọnde, pe awọn yoo fi atẹjade lede laipẹ. Ṣugbọn titi di akoko ti a n ṣe akojọ iroyin yii, a o ti i rọwọ ẹ gẹgẹ bo ṣe ṣeleri.

Leave a Reply