Gbenga Amos, Abẹokuta
Inu ọpọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ko dun si gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, bẹẹ lawọn alatilẹyin gomina naa atawọn ọmọ ẹgbẹ kan koro oju si ọrọ alufansa ti gomina Eko tẹlẹ naa sọ si gomina yii.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina tẹlẹ naa ṣabẹwo si ipinlẹ Ogun ni itẹsiwaju ipolongo rẹ fun awọn aṣoju lati dibo fun un ki wọn le fa a kalẹ lati dupo aarẹ.
Gomina Dapọ Abiọdun, igbakeji rẹ atawọn ọmọ igbimọ rẹ lo ki Tinubu kaabọ si gbọngan ti wọn ti gba a lalejo naa niluu Abẹokuta.
Nigba to di asiko ti Tinubu, ti gomina ipinlẹ Kano, Alaaji Ganduje, kọwọọrin pẹlu rẹ lo ti sọrọ pe, ‘O ti le ni ọdun mẹẹẹdọgbọn nisinyii ti mo ti n sin wọn bọ. Eleyii to jokoo lẹyin mi yii, Dapọ, ṣe o waa le sọ pe oun le da di gomina bi ko ba si temi. Mi o fẹẹ sin wọn mọ, emi naa fẹẹ di aarẹ. Yoruba lo kan, emi naa si ni ipo naa tọ si’’.
Ọrọ yii ni ọpọ eeyan binu si, bẹẹ ni awọn eeyan ti ki i ṣe ọmọ ipinlẹ Ogun ti wọn jẹ Yoruba paapaa ti n gbe e kiri lori ẹrọ ayelujara pe asọtan ọrọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu sọ pẹlu bo ṣe pe odidi gomina ipinlẹ Ogun ni ‘eleyii’ wọn ni ọrọ arifin ati ifiniwọlẹ gbaa ni. Awọn kan ni yatọ si pe Gomina Dapọ Abiọdun ki i ṣe ọmọde, ipo oṣelu pataki loun naa di mu gẹgẹ bii gomina, ko si si iru oore ti Tinubu le ṣe fun un to fi yẹ ko maa sọrọ abuku ti yoo yẹpẹrẹ gomina naa. Wọn ni iwa igberaga ni Tinubu hu pẹlu ọrọ to sọ ọhun.
Bakan naa ni Tinubu sọ pe bi ko ba si toun ni, Buhari paapaa ko le di aarẹ ilẹ Naijiria. Tinubu ni oun loun gbe Buhari wa, toun fọwọ sọya fun un, toun si ni yoo di aarẹ. O ni Muhammadu Buhari ti figba kan sọ pe oun ko du ipo naa mọ, ẹẹmẹta lo si ti ṣe e ti ko bọ si, koda, o sunkun nigba kẹta ki oun too ṣatilẹyin fun un to si wọle.
Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe asọtan ọrọ ni Aṣiwaju n sọ nitori awọn kan lo ṣatilẹyin fun oun naa to fi di gomina ipinlẹ Ekọ lọdun 1999.