Bi ko ba si temi, Buhari ko ni i di aarẹ Naijiria-Bọla Tinubu

Gbenga Amos, Abẹokuta
Emi ni Buhari fẹẹ fi ṣe igbakeji rẹ ki n too gbe e fun Ọṣinbajo, bi ko ba si si atilẹyin ti mo ṣe fun un, Buhari ko le di aarẹ Naijiria.
Oludije funpo aarẹ ilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni ti ko ba si ọrọ pe Musulumi ko lẹ jẹ aarẹ ki igbakeji rẹ naa tun jẹ Musulumi, oun ni Aarẹ Buhari fẹẹ fa kalẹ lati ṣe igbakeji rẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, lasiko to ṣabẹwo sawọn aṣoju ti yoo dibo yan ẹni ti yoo dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to n bọ.
Tinubu ni iranlọwo ati atilẹyin ti oun ṣe fun Buhari lo mu ko di aarẹ ilẹ wa, ati pe oun lo fẹẹ lo bii igbakeji rẹ lọdun 2015, ki i ṣe Ọṣinbajo.
Gomina Eko tẹlẹ naa ni orukọ mẹta loun fun Buhari gẹgẹ bii igbakeji, Yẹmi Cardoso, Wale Ẹdun ati Yẹmi Ọṣinbajo, ko too di pe Aarẹ mu Ọṣinbajo.
Tinubu ni, ‘‘Emi niyi niwaju yin ti mo si n sọ ọ laarin emi ati Ọlọrun mi pe Buhari lo pe mi pe ki n waa ṣe igbakeji oun. O ni nigba akọkọ toun dije, Okadigbo loun mu, o jẹ alafẹfẹyẹyẹ eeyan to jẹ ẹlẹsin ijọ Katọliiki, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ko dibo fun un. Lẹlẹẹkeji, o tu mu ọmọ ilẹ Ibo, Omesioke, wọn ko tun dibo fun un. Lo waa ni koda, boun ba lọọ mu Poopu wa, awọn ọmọ Naijiria ko ni i dibo fun oun. Ṣugbọn iwọ Bọla Tinubu, gomina mẹfa lo ni nikaawọ rẹ, o ko si padanu ibo ri, waa ṣe igbakeji mi.
‘‘Saraki fẹẹ ṣe olori ileegbimọ aṣofin agba, o si mọ pe ko si bi aarẹ ṣe le jẹ Musulumi, ti igbakeji rẹ yoo jẹ Musulumi, ti olori awọn aṣofin naa yoo tun jẹ Musulumi. Eyi ni wọn fi lẹdi apo pọ ti wọn gbogun ti mi.
‘‘Nitori pe mi o fẹ ki ẹgbẹ naa tuka ni mo fi sọ fun wọn pe mo ni Kristiẹni ti mo fẹe fa kalẹ, idi niyi ti mo fi fa Ọṣinbajo kalẹ.
‘‘Asiko temi naa niyi lati di aarẹ. Mo ni imọ, mo si ni iriri, ọdun bii mẹẹẹdọgbọn ni mo fi sin yin, asiko mi niyi, ẹ fun mi ni anfaani yii, ẹ dibo fun mi.
Ilẹ Yoruba lo kan, ko si si ẹlomi-in to kan nilẹ Yoruba ju emi yii lọ.’’

Leave a Reply