Wọn ti mu Bright atawọn ẹmẹwa rẹ ti wọn n digunjale l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ikọ adigunjale ẹlẹni mẹta kan, Victor Bright, Abdulraheem Muhammed ati Friday Emmanuel, lọwọ awọn agbofinro tẹ niluu Ọwọ laarin ọsẹ to kọja yii.

Awọn afurasi ọhun tọjọ ori wọn ko ju bii ọdun mẹtadinlọgbọn lọ ni wọn fẹsun kan pe wọn digun ja Hausa kan lole, ti wọn si gba ọkada Bajaj ati foonu rẹ lọ niluu Ọwọ losu to kọja.
Olori ikọ awọn adigunjale ọhun, Bright, to ba awọn oniroyin sọrọ lasiko ti wọn n ṣafihan wọn ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ko sẹni to jale ri ninu awọn, ọmọ Hausa tawọn ja lole naa ni iṣẹ akọkọ ti awọn ṣe kọwọ palaba awọn too ṣegi.
Bright ni iṣẹ telọ loun kọ laaarọ ọjọ, ati pe ẹẹkọọkan ti oun ko ba ri iṣẹ naa ṣe loun maa n tẹle awọn birikila kan jade lati ba wọn ṣiṣẹ.

O ni agbegbe iyana Ikarẹ, niluu Ọwọ, loun ti ṣẹwọ si ọlọkada ọhun lọjọ naa, ti oun si ni ko gbe oun lọ si ibi kan, bo ṣe de ile akọku kan lo ni oun da a duro, toun si ju okun si ọmọ Hausa naa lọrun latẹyin.

Bright ni ibi ti oun ati ọlọkada naa ti n jijakadi lawọn Muhammed ati Friday ti jade si awọn nibi ti wọn sapamọ si.
Nibẹ lo ni awọn ti gba ọkada ati foonu ọlọkada naa, eyi ti awọn ta fun ẹnikan to fi Ẹlẹgbẹka, nijọba ibilẹ Ọsẹ, ṣebugbe ni ẹgbẹrun lọna aadoje Naira (#130, 000).
Ẹni ti to ra ọja ole naa lọwọ wọn lo ni ọwọ kọkọ tẹ, oun lo si ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ ẹ atawọn meji yooku.

Leave a Reply