Mi o ni i ṣafikun idile to n jẹ Alaafin Ọyọ-Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi igbesẹ ṣe n lọ lọwọ lati fi Alaafin tuntun jẹ, ti awọn iran ọmọọba ilu Ọyọ kan ṣi n bẹ ijọba lati mu afikun ba awọn idile to n jọba ilu ọhun, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti rọ awọn eeyan naa lati sinmi agbaja nitori ijọba oun ko ṣetan lati jẹ ki awọn ti yoo maa jẹ Alaafin pọ si i.
Nibi aṣekagba ayẹyẹ oku Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi (Kẹta), to waye ninu papa iṣere Olivet Baptist High School, niluu Ọyọ, lo ti sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ lo ṣeto ayẹyẹ alarinrin ọhun lati bu ọla ikẹyin fun ọba rere to papoda naa.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii l’Alaafin Lamidi Ọlayiwọla waja.
Gẹgẹ bi Gomina Makinde ṣe sọ nibi aṣeyẹ ọhun, “Awọn kan kọ lẹta wa, wọn ni awọn idile kan wa to jẹ ọmọ bibi inu Alaafin akọkọ, awọn fẹ ka fi orukọ awọn naa sara awọn idile to n jọba, ki awọn naa le du oye Alaafin ninu eto ifọbajẹ to n lọ lọwọ.

“Ṣugbọn iyẹn ko ti i ṣee ṣe bayii. Ibeere ti mo bi wọn ni pe ṣe orukọ awọn idile ti wọn n sọ wọnyi wa ninu iwe ofin ọba jijẹ nipinlẹ yii, wọn ni ijọba ti fẹẹ buwọ lu u nigba kan ri. Mo ni nnkan to ti wa ninu ofin tẹlẹ nijọba wa maa tẹle lati fi Alaafin tuntun jẹ”.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, ẹni to ṣoju Gomina Isiaka Oyetọla funra rẹ, pẹlu Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan ti i ṣe Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ wa nibi ayẹyẹ naa pẹlu awọn leekan leekan nidii oṣelu bii Sẹnetọ Monsurat Sunmọnu; Alhaja Mutiat Ọladọja to jẹ iyawo Agba-Oye Rashidi Ladọja, ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri; Aarẹ-Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams; oludije dupo gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Ademọla Adeleke; awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ, eyi ti Ọnarebu Debọ Ogundoyin ti i ṣe olori wọn ko sodi, atawọn eeyan pataki, pataki lawujọ.
Agbolu ti Agbaje-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, Adekunle Adebọwale, lo ṣoju Ọọni Ile-Ifẹ, iyẹn Ọba Adeyẹye Ogunwusi; Agba-Oye Eddy Oyewọle ṣoju Ọba Lekan Balogun ti i ṣe Olubadan ilẹ Ibadan. Bẹẹ la tun ri awọn ọba alaye bii Oluwo tilẹ Iwo, Ọba Rasheed Adewale Akanbi; Iba Kiṣi, Ọba Moshood Lawal Awẹda; Ọna-Onibode ti Igboho, Ọba Abdul-Rasheed Adetoyeṣe (Jayeọla Kẹta); Onpetu ti Ijẹru, Ọba Sunday Ọladapọ Oyediran ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Mayegun ilẹ Yoruba, Alhaji Wasiu Ayinde lo kọrin atata nibi ariya ọhun; pẹlu ajọ to n ṣoju ipinlẹ Ọyọ ninu aṣa ati iṣe Yoruba, nigba ti Suleiman Ayilara ti gbogbo aye mọ si Ajobiewe kọrin ewi ki tọba-tijoye.

Leave a Reply