Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan bii aadọta ti wọn n jọsin lọwọ ninu ijọ St Francis Catholic Church, to wa ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, ni awọn afẹmiṣofo yinbọn pa lasiko ti wọn n jọsin lọwọ ninu ijọ naa ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn afẹmiṣofo naa ya wọ inu ijọ naa lasiko ti wọn n ṣe isin ọjọ isinmi lọwọ, ti wọn si da ibọn bo awọn olujọsin naa.
Bakan naa la gbọ pe wọn tun ju bọmbu sinu agbegbe ṣọọṣi naa, ti wọn si ṣeku pa eeyan ti ko din ni aadọta.
Ariwo ẹkun ati ipayinkeke lo gba gbogbo ṣoọṣi naa ati gbogbo ilu lapapọ kan. Iya, baba ati ọmọ, baba ati ọmọ, ẹgbọn ati aburo wa ninu awọn ti wọn pa yii.
Afi bii ibudo awọn alapata ni ẹjẹ eeyan n ṣan ninu ṣọọsi naa, beeyan si jori ahun, bo ba debẹ, aanu ikunlẹ abiyamọ yoo ṣe e.
Bakan naa ni wọn ni yatọ sawọn to n jọsin yii, wọn tun pa awọn to n lọ jẹẹjeẹ wọn loju ọna lati le raaye sa lọ.
Alaroye yoo maa fi bo ba ṣe n lọ si to yin leti