Bi awọn to ṣiṣẹ ibi yii ba wọnu iho ilẹ, a maa hu wọn jade-Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade

‘‘Awọn to ṣiṣẹ naa ko ni i lọ lai jiya, gbogbo ohun ta a ba ni la fi maa ṣawari wọn, wọn yoo si jiya iṣẹ buruku ti wọn ṣe yii.’’ Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, lo sọrọ naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba to n fi aidunnu rẹ han si bi awọn agbebọn kan ṣe ya wọ ṣọọṣi St Francis Catholic Church, to wa ni Opopona Ọwa-Luwa, niluu Ọwọ, ipinlẹ Ondo, ti wọn si ṣeku pa awọn olujọsin bii aadọta lẹẹkan naa.
Akeredolu ṣapejuwe iwa bi wọn ṣe pa awọn eeyan naa pe iwa ẹlẹmi-in eṣu patapata gbaa ni awọn ti wọn ṣe akọlu si ilu ti alaafia ti n jọba lati ọjọ pipẹ wa yii. O ni o jẹ ohun to ba ni lojiji gidigidi.
Gomina, ẹni to sare pada sipinlẹ Ondo lati ilu Abuja to wa, nibi to ti n palẹmọ fun eto idibo abẹle APC ti yoo bẹrẹ lọla sọ latẹnu Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlatunde, pe, ‘’Sunday ibanujẹ gbaa ni eleyii niluu Ọwọ, ọkan wa gbogbẹ gidigidi. Awọn eeyan ibi kan ti ṣakọlu si alaafia ati igbe aye alaafia ati ifọkanbalẹ ti a n gbe. Adanu nla ni eleyii jẹ fun ipinlẹ wa ọwọn.
‘‘Gbogbo ohun to ba gba la maa ṣe lati ṣawari awọn to ṣiṣẹ buruku yii, wọn yoo si jiya ẹṣẹ wọn, bẹẹ ni a ko ni i jẹ ki agara da wa lati ri i pe a fọ ipinlẹ naa mọ lọwọ awọn janduku ti wọn wọn ko ni ẹri ọkan yii.
Ni bayii, ipe ti lọ si ọdọ awọn eeyan ti wọn n gbe ni agbegbe Federal Medical Centre, to wa ni ilu Ọwọ, nibi ti wọn ko awọn to fara pa lasiko iṣẹlẹ naa lọ pe ki wọn jọwọ, waa maa fi ẹjẹ silẹ lati fi le doola ẹmi awọn eeyan naa.

Leave a Reply