Jọkẹ Amọri
Latari ikede pajawiri kan ti Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Adamu, ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe ẹgbẹ naa ti fẹnuko lati fa Olori ileegbimọ Aṣofin, Ahmad Lawan, silẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa lasiko eto idibo aarẹ ọdun to n bọ, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ni awada akọ ni ọkunrin naa n ṣe. O ni o ti fẹran ko maa ba ara rẹ ṣere ju.
Akeredolu sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to gbe sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ.
Ninu atẹjade naa, eyi ti gomina yii buwọ lu funra rẹ lo ti sọ pe: ‘‘Awọn eeyan ti pe akiyesi mi si awada akọ ti wọn ni Alaga ẹgbẹ APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, n ṣe pẹlu bo ṣe fẹẹ gbe saara rẹ kọja mọṣalaṣi nipa bo ṣe fẹẹ maa gbe igbeṣe ti ko kan an. Mo gbọ pe o ti mu ẹni ti oun funra rẹ nifẹẹ si gẹgẹ bii oludije lasiko eto idibo ọdun to n bọ.
‘‘Ikede to ṣe yii lodi si ipinnu ati ohun ti ọpọlọpọ awọn gomina ilẹ Hausa atawọn ojugba wọn lati iha Guusu fẹnu ko si. Gbogbo wa la jọ fohun ṣọkan lori eleyii. Ipo aarẹ ilẹ wa yoo lọ si iha Guusu bi gbogbo igbiyanju lati fẹnuko fa oludije kan ṣoṣo silẹ ko ba ṣee ṣe. A ko si yẹsẹ kuro ninu ipinnu yii.
‘‘Ẹ jẹ ko di mimọ pe Alaga, tabi ẹnikẹni to ba ni ero mi-in to yatọ si eleyii ṣe e lapo ara rẹ ni. Irinajo ti ko ni i mu ohunkohun jade lo n rin funra rẹ, leyii ti awọn onilaakaye yoo ri bii ohun to lewu.
Loootọ ni a n ṣọfọ, ṣugbọn a ko tori eleyii gbagbe pe agbara gbọdọ pada si iha Guusu, lori eleyii la si duro le lori.’’ Akeredolu lo sọ bẹẹ.