Nitori ibo to n bọ, Oyetọla bẹ awọn tinu n bi l’Ọṣun lati fọwọ wọnu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti inu n bi nipinlẹ naa lati fọwọ wọnu, ki wọn gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ latẹyinwa, ki wọn si ṣiṣẹ fun aṣeyọri ẹgbẹ naa ninu idibo oṣu to n bọ.
Niluu Mọdakẹkẹ, ni gomina ti sọrọ naa lasiko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun sọrọ nibi ipolongo ibo fun saa keji rẹ lọfiisi.
Oyetọla ni ti oun ba wọle fun saa keji, oniruuru anfaani ni yoo wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa nijọba ipinlẹ ati lọdọ ijọba apapọ, o si rọ wọn lati ri i pe wọn gba kaadi idibo wọn lati fi dibo fun ẹgbẹ APC.

O ni, “Mo mọ riri ifọwọsowọpọ yin lasiko idibo abẹle to waye kọja. Ni bayii, a fẹẹ lọọ koju awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in ninu idibo. Yatọ si ẹgbẹ oṣelu APC, ko si ẹgbẹ kankan to tun wa nipinlẹ Ọṣun mọ. Ayederu ni awọn to ku.

“Inu mi dun tori pe ẹ tu yaaya jade lati gba mi. Mo ṣeleri pe mo maa pari oju-ọna Famia ti a n ṣe lọwọ. Mo tun gbọ pe awọn nnkan amayedẹrun kọọkan n jẹ ilu yii niya, a maa gbiyanju agbara wa. Mo rọ yin ki ẹ lọọ gba kaadi idibo yin, ki ẹ si tete de ibudo ibo lọjọ idibo lati tẹka fun ẹgbẹ APC.

“Mo bẹ gbogbo awọn ti inu n bi lati fọwọ wọnu. Iṣejọba ki i ṣe awada rara. Mo gbọ, mo mọ, mo si tun kawe. Ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni dẹruba yin, ẹgbẹ yin lo wa nijọba”.

Leave a Reply