Faith Adebọla
Ilumọ-ọn-ka adẹrin-in poṣonu onitiata ilẹ wa nni, Wale Akorede, tawọn eeyan mọ si Okunnu, ti fi aidunnu rẹ han si bi nnkan ṣe ri ati ipo ti orileede yii wa, epe nla lo ṣẹ fawọn to kopa ninu akoba ọhun, bo si ṣe n ṣepe lawọn ololufẹ rẹ n ṣe amin si i.
Lori ikanni instagiraamu rẹ ni Okunnu gbe fidio kan si lopin ọsẹ yii, o si kọ ọrọ sẹgbẹẹ fidio naa, ṣugbọn awọn ọrọ naa ki i ṣe ọrọ apanilẹrin-in rara, ọrọ to ka Okunnu lara ni, o ni:
“Naijiria yii o daa. Boya ọkunrin ni o, abi obinrin, ọmọde tabi agbalagba, to lọwọ si bi orileede yii ṣe di ohun to da lonii yii, niṣe laye tiwọn naa maa bajẹ lati iran de iran. Gbogbo awọn to jẹ ki Naijiria bajẹ bo ṣe ri yii, igbesi aye tiwọn naa maa bajẹ lati iran de iran ni, tori ipo ti wọn fi wa si yii buru jọjọ.”
Okunnu tun sọ pe: “Ọrọ ko ti i ka mi lara to bayii ri. Nibo la n lọ lorileede yii gan-an. Ọjọ wo la too fẹẹ gbadun ara wa gẹgẹ bii ọmọ orileede Naijiria. Na waa oo, eyi ga o.”
Bẹẹ ni Okunnu sọ.