Awọn lọọya mẹta gba kootu lọ, wọn ni ki INEC wọgi le Tinubu, Atiku ati Obi gẹgẹ bii oludije

Faith Adebọla

Wọn ni oriṣiiriṣii ọbẹ la a ri lọjọ iku erin, bẹẹ lọrọ ri lasiko yii pẹlu bi ẹsun, ipẹjọ ati idajọ ṣe n waye lagbo oṣelu latari eto idibo gbogbogboo 2023 to n bọ lọna. Ni bayii, awọn agbẹjọro mẹta kan ti wọ ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, lọ sile-ẹjọ, wọn ni ki kootu paṣẹ fun ajọ naa lati wọgi le bi wọn ṣe yan awọn oludije funpo aarẹ mẹta kan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Alaaji Atiku Abubakar ati Ọgbẹni Peter Obi.
Tinubu ni oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Atiku ni ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP), fa kalẹ, nigba ti Peter Obi yoo dije labẹ asia Labour Party (LP).
Ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba FHC/ABJ/CS/1004/2022 eyi ti wọn fi pe ẹjọ naa sile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, awọn olupẹjọ naa, Amofin Ahmed Yusuf, Amofin Ataguba Aboje, ati Amofin Oghenovo Otemu, ni iyansipo awọn Tinubu, Atiku ati Obi ko ba ilana mu, awọn ẹgbẹ oṣelu to si fa wọn kalẹ ko tẹle ilana to yẹ.
Yatọ si ajọ Independent National Electoral Commission (INEC) ti wọn pe lẹjọ, wọn tun darukọ Minisita feto idajọ, Abubakar Malami, ẹgbẹ oṣelu APC, PDP ati LP gẹgẹ bii olujẹjọ.
Agbẹjọro awọn olupẹjọ ọhun, Amofin Ataguba Aboje, ṣalaye ninu iwe ipẹjọ naa pe awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta yii ti tapa si ofin ilẹ wa ti ọdun 1999, ati ofin eto idibo ti ọdun 2022.
Lara ẹsun ti wọn ka si wọn lọrun ni pe wọn kuna lati yan oludije ti yoo ṣe igbakeji aarẹ ki eto idibo abẹle gbogbogboo, nibi ti wọn ti fa oludije funpo aarẹ kaluku wọn kalẹ too waye, gẹgẹ bi ofin ti wi.
Wọn tun fẹ kile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ boya niṣe lo yẹ kawọn ẹgbẹ oṣelu maa yan igbakeji oludije fun ipo aarẹ sipo, abi o yẹ ki wọn maa dibo yan wọn, nibaamu pẹlu ohun to wa ni isọri kọkanlelaaadoje (131), ikọkanlelogoje (141) ati ikejilelogoje (142) iwe ofin ilẹ wa tọdun 1999.
Wọn ni kile-ẹjọ pinnu boya o tọna tabi ko tọna fun ajọ INEC lati gba orukọ oludije funpo aarẹ ti ko si igbakeji rẹ lẹgbẹẹ rẹ lasiko idibo abẹle ti wọn fi yan an sipo wọle.
Ile-ẹjọ ko ti i sọ asiko ti igbẹjọ yoo waye lori ẹjọ yii, ṣugbọn wọn ti fi ẹda iwe ipẹjọ naa ṣọwọ sawọn olujẹjọ atawọn ti ọrọ naa kan.

Leave a Reply