Kayeefi kan ree o! Wọn ba aadọta awọn ọmọ keekeeke ninu ajaalẹ ni ṣọọsi kan l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Bii omi lawọn eeyan n rọ lọ si adugbo kan ti wọn pe ni Valentino, niluu Ondo, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yìí, latari iroyin ojiji kan ti wọn gbọ pe wọn ṣawari ajaalẹ ninu sọọsi The Whole Bible Believer, nibi ti wọn n ko awọn eeyan pamọ si.
Níbi tọrọ ọhun ka awọn eeyan lara de, diẹ lo ku ki awọn eeyan tinu n bi dana sun oludasilẹ ṣọọsi ọhun, ẹni ti wọn porukọ rẹ ni Pasitọ Anifowoṣe David ati igbakeji rẹ, Josiah Peter, kawọn ọlọpaa too sare ko wọn lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, obinrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Abilekọ Elizabeth Reuben lo lọọ ba oludasilẹ sọọsi naa pe ko yọnda ọmọ oun obinrin to wa nikaawọ rẹ ko le lanfaani ati ba wọn kopa ninu idanwo aṣekagba oniwee-mẹfa ti wọn fẹẹ ṣe nipinlẹ Ondo laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide.
Ṣugbọn dipo ki pasitọ ọhun fi ọmọ ọlọmọ silẹ, ṣe loun ati awọn alatilẹyin rẹ kan ki iya naa mọlẹ, ti wọn si lu u lalubami ki wọn too tun gbe e ju sẹyin ọgba ile-ijọsin wọn.
Eyí lo bi iya ọmọ naa ninu to fi lọọ fi ẹjọ sun awọn ajafẹtọọ kan niluu Ondo, ohun kan naa ti wọn ṣe fun iya ọmọ naa ni wọn tun ṣe fun ẹni to lọọ pe wa lati waa kọya fun un.
Ajafẹtọọ ọhun, Ọgbẹni Ọmọlayọ Ọmọlasọ, ninu alaye to ṣe fun ALAROYE, o ni ohun ti oun ro kọ loun ba nigba toun de ṣọọṣi naa nitori pe ṣe ni wọn ti geeti ibẹ pa mọ awọn to wa nigbekun pasitọ ọhun mọ inu ile.

O ni oun oun ṣaa rapala wọle lẹyin ti oun ti kan geeti titi ti oun ko ri ẹni dahun.
Ọmọlasọ ni ohun to ya oun lẹnu ju ni ti pupọ awọn ti oun ri ti wọn tun kun Pasitọ Anifowoṣe lọwọ lati lu oun bii ẹni lu bẹmbẹ, ki wọn too tun ju oun lati ori fẹnsi sita.

Lẹyin eyi lo ni oun lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti ni teṣan Fagun, ti ọga ọlọpaa teṣan ọhun atawọn ọmọlẹyin rẹ kan si tẹle oun lọ, ṣugbọn to jẹ pe ṣe lawọn tun sa kuro latari ija ti wọn tun gbe ko awọn loju, ninu eyi ti ọga ọlọpaa ọhun gan-an ti fara pa.
O ni nigba ti awọn lọọ ko awọn ẹṣọ Amọtẹkun, sifu difẹnsi atawọn ọlọpaa adigboluja kunra lawọn ṣẹṣẹ kapa awọn pasitọ naa atawọn ọmọlẹyin rẹ, ti awọn si raaye wọle sinu ṣọọṣi ọhun gan-an.
Ọga awọn ajafẹtọọ lagbegbe Ondo ọhun ni iyalẹnu nla lo jẹ fawọn lati ri ọgọọrọ awọn eeyan atawọn ọmọde tọjọ ori wọn bẹrẹẹ lati bii ọmọ ọdun marun-un, nibi ti wọn ko wọn si ninu ajaalẹ kan to wa ninu ṣọọṣi naa.
O ni apapọ iye awọn eeyan ti awọn ba ninu igbekun pasitọ naa le ni aadọta, alẹ ọjọ naa lo ni awọn ti ṣeto ati ko gbogbo wọn lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ondo.

Ilẹ ọjọ kejì, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide ko si ti i mọ tan ti wọn fi tun ko gbogbo wọn lọ si olu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo to wa l’Akurẹ.
Ninu ọrọ ti ọkan ninu awọn obi ọmọ ti wọn ṣawari naa ba wa sọ, abilekọ ọhun to porukọ ara rẹ ni Kẹhinde Oluwafẹranmi ni ọmọ oun mẹrin ni wọn wa lara awọn ọmọ to wa ninu igbekun Pasitọ Anifowoṣe.

O ni oun ti figba kan gbe ọkunrin to n pe ara rẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun ọhun lọ si kootu lori ọrọ awọn ọmọ oun to wa lakata rẹ ti ko si fẹẹ yọnda wọn.
O ni ṣọọṣi naa loun ati ọkọ oun kọkọ n lọ loootọ, koda ibẹ lo ni oun bi gbogbo awọn ọmọ oun si, ti akọbi oun si ti to bii ọmọ ọgbọn ọdun, nigba ti abikẹyin ko ti i ju ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lọ.
Abilekọ Kẹhinde ni ọsan kan oru kan loun sa kuro ni ṣọọṣi naa nigba toun ṣakiyesi pe oludasilẹ awọn ti n yiwọ pada, ati pe ọpọlọpọ igba lawọn asọtẹlẹ eke maa n waye nibẹ.
O ni pasitọ meji ni wọn ti fo sanlẹ ti wọn ku lojiji ninu ijọ naa nigba ti oun ṣi wa nibẹ, ti ko si sẹni to le sọ pato ohun to ṣeku pa wọn.
Iya ọlọmọ mẹrin ọhun ni oun pada sa kuro lọdọ pasitọ naa nigba ti asọtẹlẹ irọ n jade lemọlemọ pe oun gbọdọ fi iṣẹ ounjẹ ti oun n ta silẹ ki oun si waa maa gbe inu ṣọọṣi lai ṣe iṣẹ kankan mọ.

O ni gbogbo akitiyan oun lati igba naa pe ki pasitọ naa yọnda awon ọmọ oun foun ko so eeso rere nitori pe oun ti wọn n tẹ mọ oun leti ni pe oun ko laṣẹ lati yan le wọn lọwọ mọ, niwọn igba ti wọn ba ti pe ẹni ọdun mejidinlogun.
Yatọ si akọbi rẹ to ti kawe gboye, o ni ṣe lawọn ọmọ oun yooku kọ jalẹ ti wọn ko lọ sile-iwe mọ latari iwaasu ti Pasitọ Anifowoṣe n wa fun wọn pe ko pọn dandan ki wọn kawe nitori Jesu ko ni i pẹẹ de mọ.
O ni akẹkọọ ile-iwe awọn nọọsi ni ọkan ninu awọn ọmọ oun, ipele kẹta ti i ṣe ipele aṣekagba lo wa to fi yari pe oun ko kawe mọ latari wiwa Jesu to n sun mọ etile.

Ileewe girama kan niluu Ondo lo ni a igbẹyin oun wa ki pasitọ naa too ja a gba mọ oun lọwọ, ti ọrọ ẹ̀kọ́ rẹ ko si lojutuu mọ lati igba naa.

O ni bẹẹ loun n bẹ ijọba ki wọn ba oun gba awọn ọmọ ti oun ti nawo iyebiye le lori kuro lakata pasitọ naa ko too ba gbogbo wọn laye jẹ tan.
Ohun ta a gbọ lati ẹnu awọn araadugbo ta a tun fọrọ wa lẹnu wo ni pe Pasitọ Anifowoṣe ki i gba kawọn ọmọ to ba ti ha sinu igbekun rẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ wọn, ọrọ to maa n ba wọn sọ ni pe wọn ko nilo ati maa yọ ara wọn lẹnu rara, a a ni ki wọn jokoo pa sinu ṣọọṣi oun ki wọn si maa reti bibọ Jesu nikan.
Wọn ni ọmọ pasitọ naa meji ni wọn ti kẹkọọ gboye ni Faṣiti imọ Iṣegun to wa niluu Ondo, ṣugbọn ti ki i fẹ kawọn ọmọ ijọ rẹ kawe.
Ọpọ awọn araadugbo ni wọn ni ọwọ pasitọ naa ko mọ rara, wọn ni oogun ati tira lo fi n mu awọn ọmọ ọlọmọ mọlẹ ti wọn fi n ri awọn obi wọn sa.

Leave a Reply