Adajọ ni ki wọn sanwo ‘gba ma binu’ fawọn aṣofin Ondo

 Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga kan to wa l’Akurẹ ti paṣẹ fun ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lati da awọn aṣofin mẹta ti wọn da duro pada lẹyẹ-o-sọka.

Igbakeji abẹnugan ile, Ọnarebu Irọju Ogundeji, to n ṣoju awọn eeyan Odigbo kin-in-ni, Wale Williams, lati ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo keji ati  Favour Tomomewo, to jẹ aṣoju awọn eeyan Ilajẹ keji ni wọn da duro ni nnkan bii oṣu meji sẹyin, lẹyin ti wọn kọ lati kọwọ bọwe iyọnipo Igbakeji Gomina ipinlẹ naa, Ọnarebu Agbooọla Ajayi.

Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Ademọla Bọla, dajọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja, pe ohun to lodi sofin patapata ni bi wọn ṣe n di awọn aṣofin mẹtẹẹta naa lọwọ lati ṣoju awọn eeyan to dibo yan wọn gẹgẹ bii aṣofin.

Onidaajọ Ademọla paṣẹ pe ki wọn da awọn ti wọn da duro naa pada kiakia, bẹẹ ni wọn gbọdọ tun san miliọnu marun-un naira fun ẹnikọọkan wọn gẹgẹ bii owo gba ma biinu.

 

Leave a Reply